Sunday, 21 August 2016

URHOBO –ISOKO




     Urhobo ati Isoko je ede meji to wa ninu ebi kan naa, won si sunmo ara.Awon ede mejeeji ni o ni bibeli ati  iwe orin won. Baka naa won ni awon iwe litireso orisirisi. Dikisonari wa ni ede Urhobo. Ede Okpe, Urhobo ati Uvwie je awon ede ti o yato meta ti awon eya kan ti an pe ni Urhobo maa nso ni ipinle Delta, ni guusu orile ede Naijiria. Asa kan naa ni gbogbo Urhobo ni sugbon ni ti  eto oselu, idi igi merinlelogun ni won pin si. Ilu meji lo nso Uvwie. Ilu kan lo nso Okpe (awon ni won si poju niye). Ede Urhobo ni awon ilu mokanlelogun to ku n so.
     Ilana ede Agbarho ni awon ilu merinlelogun naa fi nko ede won sile. Adalu ede oyinbo(pidgin) ti ropo pupo pelu ede Urhobo nitori naa awon ojogbon woo wi pe ti won ko ba wa ba nkan se, ede naa (Urhobo) le d'oun igbagbe.

No comments:

Post a Comment