Aki
I pelu obo jako je ijinle oro Yoruba ti a n lo lati je ki eniyan mo wi pe aani
lati huwa aito pada si eni to huwa aito si wa, eniyan kan le huwa buburu si wa,
owe yii lafin da iru eniyan bee loun wi pe aki i pelu obo jako iyen ni wi pe bi
ori ti e ko ba pe, iyen koso wi pe, ki emi naa huwa aipe ori.
Oro
yii lomu mi ranti oro kan to sele si mi nigba kan ri, nibii odun bii meedogun
seyin omobinrin kan wa ti ajo ngbe adugbo, ti a si jon lo si ile ijosin kan
naa. Ko si ajosepo to koja ki akira wa la dugbo lo. Sadede ni mo nko awon omo
kilaasi mi ni yara ile eko ojo isinmi ni soosi, omobinrin wa siwaju mi nibiti
moti nko awon omo, o si bere si ni pariwo mo mi, oni won so wi pe mo maa n rojo
oun ati idile oun kaakiri, wi pe ti oun ba mumi oun ase mewaa fun mi. Awon
eniyan gan an ni won roo mi kuro lodo mi.
Oro
yi se mi ni kayefi de bi wi pe mi o le tesiwaju lati ko awon omo ti mo nko mo.
Mo ni ki elomiran maa ba ise naa lo. Oro naa dun mi de gogo orun, nitori wi pe
mi o se nkankan fun omobinrin yi ati awon ebi re. Yoruba bo won ni bi na ko
lawo kole goke odo, ninu isin lojonaa, omobinrin kan wa ti o je ore eleyii to
pariwo mo mi. bi isin se e nlo, omobinrin naa fiwe pelebe ranse simi, o ko si
be wi pe ki nma binu gbogbo nkan to sele. Ni eyi ti mo si mo wi pe oun lo sise
laabi naa.
Leyin ojo di e, Oluso aguntan ijo pe, awa mejeeji won gbo tenu wa, won
siro wa wi pe ki oro naa pari si be. Mo gbe oro naa kuro lokan, onikaluku ba
tire lo. Nigba to maa fi to bi odun kan si meji, omobinrin naa lo sile oko,
oloyun, o siba oyun naa lo sorun.
Nigba tii oro naa sele laarin wa nigba naa mi o fejo sun nile, nitori mo
mo wi pe wahala nla lo maa da sile nile laarin idile mejeeji. Nijo ti mo gbo
nkan buruku to sele si omobinrin yii, mama mi lo so fun mi. Inu mi baje o dun
mi o ka mi lara. Ni ojo naa ni mo salaye nkan to sele laarin emi ati omobinrin
yii fun mama mi. Oka won lara wi pe, ka ni awon gbo ni, wahala iba so. Mo wa so
fun won wi pe ka ni mo ti so fun won, ki won lo pariwo lodo awon omobinrin naa,
leyin naa ki nkan to sele si omobinrin naa wa sele. Se won o ni so wi pe,eyin
te e wa pariwo lo pa won lomo. Mama mi naa wo wi pe ooto ni mo so o.
Tara
obinrin naa ti wa lara e, kii se wi pe toripe o huwa buruku fun mi niwaju
olorun, sugbon teeyan ko ba sora, ti oro ba sele won le foro koro, koo yan
lorun. Nitori naa ni mo se gba wi pe AKI I PELU OBO JAKO.
No comments:
Post a Comment