Saturday, 6 August 2016

Bi o jo ewure ba pe



                                                                            



Bi ojo ewure ba pe je owe yoruba tii ipari re si je a ni ko si oun ti alapata yoo fi oun se, a maa nlo owe yii lati se ikilo fun eni too nse afojudi si oun to lewu to wa niwaju re. Orun lile, aimokan tabi igberaga ni o saba maa n fa iru eyi.

Bi apeere, okunrin wooli ti o wi pe oun le wole to kiniun lo bi Danieli se too lo ninu bibeli, sugbon oun gbagbe wi pe iyato wa laarin didan olorun wo ati idanwo. Idanwo lo de ba Danieli, eleyii ti ko reti, olorun si koo yo ninu re, nitori wi pe o gbeke re le. Sugbon, wooli yen ko si ninu isoro, oun lo yo tan to n wa bekun bekun kiri. O fe dan olorun wo ni, olorun kii  si leyin enito ba danwo, idi niyen ti kiniun naa fi fa a ya.
       Apeere miiran ti mo tun ri, ni ti Samusoni alagbara ninu bibeli, awon obi re ti kilo fun un wi pe ki o mase fe omobirin Filistini alaikola naa, sugbon ko gbo si won lenu, o tesiwaju lati maa ba omobinrin naa rin, nigba to ya omobinrin yi naa lo mu isubu re wa, idi ni yen ti awon baba wa fi bo ti won ni bi ojo ewure ba pe  a ni ko si oun talapata fe foun se. Idi ti won fi lo ewure ni wi pe, ewure je eranko alagidi.
      Apeere keta ti mo ni niti omode kan ati awon obi re,  oun ati iya re sin baba re lo si idiko oko ofurufu nitori wipe baba re fee rinrin ajo, bi baba re ti dagbere fun won to fe fi won sile, omode naa fi ede oyinbo beere lowo baba re wi pe, se kii se wi pe dadi mi fe wo nu oko to wa lookan yi, baba ati iyaa re daa loun wi pe beeni, o ni se won o mo wi pe oko baalu yen maa ni ijanba  to ba gbera ni, won fun un le si wi pe ko si oun kankan to maa sele. Baba re si fi won sile lati maa tesiwaju. Ni kete ti oko yi gbera, ko ti to iseju meta ti oko naa fi lo kolu apata kan lookan ti oko naa si lanaa, gbogbo awon to wa ninu oko naa si jona. Olorun fi asiri oun to ma sele han omode naa sugbon awon obi re ko kaa si, won ri gege bi oro omode,  won ko ti ogbonyin sii. O dara lati ni akiyesara.

No comments:

Post a Comment