Tuesday, 16 August 2016

OJA ILU MI




Oja je ibi ti karakata ti ma n sele. Awon ti won ni oun jije tabi oun eelo yoo gbe won wa si oja, awon ni a npe ni oloja. Bee ni awon ara ilu ati enikeni ti o ba fera oja yoo wa si inu oja lati wara.
     Oruko oja to wa ni ilu mi ni oja Irede, oruko ilu mi ni Awade . O wa lara awon ilu ti a kopo si abe Egbado ti a tun pe ni Yewa. Orisirisi awon oja miiran tun wa ni ilu wa. Awon naa ni oja ita oba, oja sawonjo, oja ilusa ati bee beelo.
     Ojo karunkarun ni won maa nna ja Irede. Aarin ilu Awade  ni oja naa wa. Oba Ajelanwa ni itan sope o da oja naa sile nibi Ogorun odun seyin. Inu oja yinaa ni idiko awon onimoto wa. Moto to lo si orisi ilu ni o wa nibe. Nibe naa ni awon moto tii won ngbe oja wa lati igberiko, lati wa se oro aje ninu oja nla.
     Niso niso ni awon oja naa wa. Biriki ni won sifi ko awon iso towa ninu oja naa. Biso alata sewa ni iso oni gaari wa. Awon iso miiran ni: Elelubo, alagbo,onisu,elepo ati bee beelo. Iso kookan  ni o si ni olori iso. Gbogbo oja si ni iya loja ati awon alakoso ati oloye oja.
    Oja yii je oja to gbajumo, to si je ilumoka kaakiri ile Yoruba. Enikeni to ba feera gaari, epo tabi egusi ledinwo mo wi pe oja Irede ni o ye ki awon ti rii ra. kosi alajapa kan ti yoo so pe oun o mo Irede. Ti kii ba se ti oja yi ni ko se ni ti yo mo ilu wa. Oja yii lo je ki amo agbegbe naa. Oja yi lo fun ilu yi lokiki. Oun lo je ki ilu naa ni asaaju nile igbimo asofin. Oun naa lo mu ki eto mayederun ijoba fi de odo ti won naa.
     Nitori oja yii se pataki fun eto oro aje ipinle Ogun ati ibile ariwa Yewa. Ijoba ti ba won da oda si opolopo ona ti o wo oja naa. Ilu Awade funrare si ngbadun ina ijoba. Omi igbalode wa fun won. Ijoba si fun won ni ile eko alakobere ati ti girama.
     Awon asaaju oja Irede naa sin se bebe. Won ni awon owo oja ati iso ti won maa ngba lowo awon oloja. Eleyii ni won fin tun oja yii se. Won kii duro de igba ti ijoba to wa bawon da soro ki won to gbe igbese lori re. Owo yi ni won fi nsanwo awon agbale oja ati awon olode. Ninu re naa, won a yo ti awon oloye oja ati t' Oba ati awon ijoye won, ninu re naa ni won tin se awon etutu ati awon asa isembaye to ba ye ki won se.
     Bi eniyan yoo wa raja ni oja Irede, o gbodo jiwa ni. Afemojumo loja. Nigba yii, eeyan yoo ri oja ra lopo. Owo eni ni oja ni eniyan yoo ti ra ledinwo. Sugbon ti ile ba ti nmo ki eniyan to wara oja, yoo ti ma dowo awon alarobo ti won a ra lati  tunta.  Awon wonyii yoo ra ledinwo lowo oni nkan won awa gbe owo lee lati tun ta.
       Isoro akoko ti mo ri wi pe oja yi ni ni pe, bi won se da oda si awon ona ti o wonu oja yi to, ko si oda ninu oja yii, ti ojo bawa ro ni ki ewa wo arisa oja yi. Erofo yoo ti poju. Awon oko yoo ma wa ri wole. Eleyii kobo ju mu, ki ijoba bawa tun ona inu oja yi se.
     Isoro keji ni wi pe, bi eniyan bara oja sile. Ibaaje oja sile meji, awon kan bi egbe omo oni moto yoo de lati wa gba owo lori oja te e ko si le. Iye ti won si maa ngba maa nju tabi ko fere to iye teeyan fira oja yen nigba miran lo. Osi da miloju wi pe kii se gbogbo owo ti won ngba yii lo nde odo ijoba.

1 comment:

  1. Please can u write Atijo alapejuwe Lori oja ale, ejo

    ReplyDelete