Saturday, 6 August 2016
ISE TI EDO NSE LARA (FUNCTIONS OF THE LIVER)
Edo je eya ara inu ti o tobi julo. Apa otun ni abe dayafurami (diaphragm) lo wa ninu ikun. Edo agbalagba maa n won to poun meta (3pounds).
Apa meji ni edo pin si. Edo otun ati edo osi. Edo apa otun tobi ju ti osi lo. Awon seeli(cells) to n sise ninu edo ni a n pe ni epatosaiti(hepatocytes). Ti edo ba ni ijanba awon seeli inu edo wonyi le dinku niye. Edo maa n hu pada ti won ba ge apakan kuro ni pa ise abe tabi ti apakan ba kuro nitori ijanba.Edo ni agbara lati ropo eya re to baje sugbon ti ijanba naa ba ju apa re lo, o le faa ki edo naa kuna tabi ko ku(liver failure).
Ojuse edo po ninu ara. Awon to je ojuse gboogi ti edo nse ni wonyi:
O n pese omi inu orooro
o n gba idoti ara jade
oun ni on gba awon aloku omi ororo, omi ora, omoonu ati oogun kuro lara.
oun se awopale awon ounje bi ora, fitami ati awon oun je afunnilagbara(carbohydrates)
oun ta awon ojise ara kan (enzyme activation)
oun pese pulasima puroteni bii alibumini ati awon iranse ara to n di oju egbo,
oun fo oro kuro ninu eje(detoxification), o si n so eje di titun
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment