Monday, 15 August 2016

ERE IWANWARA (Consequence of hasty judgement)




     Se awon agba bo wonni suuru ni baba iwa. Akori mi oni dori awon lokolaya kan.Oju omo pon awon mejeeji pupo. Awon mejeeji si je oyinbo. Nigbatii o ya ti aayun omo nyun won, won pinu lati ra aja kekere kan lati ma se toju re nipo omo. Aja yi naa bere sini dagba. Opolopo igba ni o si ti gba awon olowo re lowo ewu awon adigunjale nitori wi pe aja naa tobi, o si ja fafa.

     Nigba to ya olorun gbo adura awon loko laya naa, won bimo okunrin. Inu won dun lopo, won si n sike omo naa. Eleyii mu ki ife ati akoko ti won ni fun aja ti won fi se omo tele dikun. Eyi ko si mu inu aja naa dun.
     Ni ojo kan, awon loko laya yii fi omo won sinu yara, won si lo siwaju ita lo naju, bi won se wa npadabo wonu ile, won ri ti aja won nbota lati ona to lo si nu yara  tomo won wa. Gbogbo enu aja naa kun fun eje, atori ate nu. Okan won folo. Won lero wi pe aja na ti lo pa omo won je. Won o se mini semeji, won yibon to wa lowo won fun aja naa lori, osi ku loju ese.
     Nigbati won wonu yara won ba ori ejo nla ti aja naa ti pa legbe omo won toti sun fonfon. Owo won bo, ibi ti won foju si ona kogba be lo. Ore laja yi se fun won, won bere si ni sunkun sugbon e pa ko boro mo. Aini suru ati iwanwara ti mu ki won pa oloore won.

No comments:

Post a Comment