Awon
wonyi ni ara Gbagyi tabi Gbari. Awon ni
won wa ni aarin orile ede Naijiria. Won to milionu meedogun niye. Ede meji lo
wa laarin won. awon Hausa ati awon Oyinbo alawo funfun ni won bere si ni pe won
ni Gwari ni gba atijo, sugbon oruko ti o te awon gan an lorun ni Gbagyi. Won
ngbe ni awon ipinle Niger, Kaduna ati Abuja, Nasarawa ati Kogi. Ise agbe ni won
yan laayo.
Oye oba won ni Osu. won tun
sise ode, ise ikoko mi mo,odo ati omo odo sise.
Won po si kachia (Kaduna), Minna, Kwakuti, Kwali, Wushapa, Bwaya
(Buhari), Suleja ati Paiko. Awon Ojogbon onitan kan gba wi pe ogun Jihadi awon Fulani
lo tu won Kaakiri. Ijoba apapo lo le won kuro lori ile abinibi won, ti won so
di ti igbalode.
Awon niwon ni ori oke Zuma
ti o di ti ijoba lo ni.Awon ara Gbagyi je eniyan tutu ti kii fa wahala. Ede
meji ti won nso ni Gbari ati Gbagyi.
No comments:
Post a Comment