Awon
ara Ibibio wa lati guusu-ila oorun(south east) orile ede Naijiria. Won tan mo
awon Anaang, Efik ati awon Igbo. Ipinle Akwa ibom ni won posi julo.Nitori wi pe
awon Ibibio po, awon ni won dari eto oselu ipinle Akwa ibom julo, sugbon won
maa npin ijoba pelu awon Anaang, Eket ati Oron. Ki orile ede Naijiria to parapo
di orile ede ni awon Ibibio ti ni eto ijoba ara won. Nitori wi pe ipinle Akwa
ibom sunmo orile ede Cameroun, awon apakan Ibibio, Efik ati Anaang wa ni Naijiria,
awon kan si wa ni Cameroun. Ise epo sise ni ise won tori awon igi ope to po
nibe.
Loni, eyi to
poju ninu awon Ibibio je onigbagbo. Mary Slessor lo dekun asa pipa awon ibeji
laarin awon Ibibio, nitori eleyii je asa won tele. Won maa ngbe iru awon ibeji
bee lo si iru igbo buburu fun won lati ku danu. Eya mefa ni Ibibio pin si.