Awon ara itsekiri je awon eya to wa lati apa Niger
Delta lori le ede Naijiria, ni ipinle Delta. Awon omo itsekiri leni million kan
niye. Won wa ni guusu Warri, Ariwa Warri ati guusu – iwo- orun Warri. Awon omo
Itsekiri naa wa ni Edo, Ondo, Sapele, Benin, Port Harcourt ati Abuja. Awon omo
Itsekiri maa n pe ilu won ni “Iwerre”, won mu oruko yi lati ara ewe “ewerre”,
ni ede bini ti o tumo si inu rere ati alaafia. Agbegbe yi je okan pataki lara
ilu ti o ni epo robi ati afefe gaasi, osi tun ni ibi ifopo robi.ilu Warri si je
ilu nla ti o ni orisirisi eya, o si je olu ilu fun oro aje ati ile ise nlanla
ni gbogbo Niger Delta. Ede itsekiri je ede to sunmo ede Yoruba ati Igala. Awon
ara itsekiri ni awon eni akoko ti o koko ni ajosepo pelu awon Oyinbo Potogi
(Portuguese) lori le ede Naijiria.
Awon elesin kirisiteni lo
poju ninu won. Opolopo awon ti won je omo itsekiri je awon ti awon obi won ni
adalu orisirisi eje ninu. Olu ilu itsekiri ni Ode- itsekiri. Awon omo itsekiri
maa n kawe, won si lowo lowo. Won wa lara awon ti won koko ka we gboye ni orile
ede yi. Bi apeere: Olu ti Warri. Awon omokunrin itsekiri maa n wo saati alapa
gigun ti won n pe ni kemeje, won si maa nro iro jooji (George wrapper), won a
si de fila to ma n ni iye ninu. Awon obirin won lo maa n wo bulaosi ti won si
maa nro iro jooji (George) won si maa n we gele didan ti o maa ni owo eyo lara.
Ise apeja ni se won.
Awon Eeyan Pataki to je omo
ilu itsekiri
Ø Emmanuel
Uduaghan (Gomina ana ni Delta)
Ø Festus
Okotie- Eboh (Oloselu).
Ø Lizzy
Gold Onuwaje (Elere Oritage)
Ø Amatosero
Ani (Elere oritage)
Ø Amaju
Pinnick (Alaga NFF)
Ø Grace
Alele- Williams
Ø Ladi Utieyione
Ø Ayo
Oritsejafor (Oluso aguntan)
Ø Oritse
Femi (Olorin)
Ø Omawunmi
(Olorin)
No comments:
Post a Comment