Sunday, 9 October 2016

ADO EKITI 2



       

 Ado Ekiti je ilu ti won ngbin isu, ege, agbado, oka, tobako ati ewe owu. Iwadi sayensi fi han gbangba wi pe awon eniyan ti ngbe ni Ado Ekiti ni ole ni egberun odun mokanla seyin(11,000 years ago).
      Awon omobibi Ado maa nje akinkanju ati jagunjagun to gboya. Lara awon akikanju won ninu itan ni Ogbigbonihanran ti Idolofin, Ogunmonakan ti Okelaja, Fasawo(Aduloju) ti Udemo ati Eleyinmi Orogirigbona ti Okeyinmi. Itan so wi pe omo iya kan naa ni Oba Ado Ekiti ati Oba Bini. Awon mejeeji je omo Oduduwa. Oye Oba won ni Ewi. Ado Ekiti di Olu ipinle Ekiti ni ojo kinni osu kewaa, 1996 ti won da Ipinle Ekiti sile.

No comments:

Post a Comment