Akure je ilu nla ni ile Yoruba, ni orile ede Naijiria. Oun ni ilu
toto bi julo ni ipinle Ondo. Oun si tun ni Olu ilu ipinle Ondo. Awon ti o wa
ninu ilu naa je 484798 ni odun 2006. Ni ilu Akure ni awon onimo ijinle Sayensi
tiri egungun eniyan to dagbajulo ni gbogbo iwo oorun Afirika. Iwadii so wi pe
ojo ori egungun naa je odun to le ni egberun mokanla. Itan so wi pe Omoremi
Omoluabi to je
omoomo fun Oduduwa lo da ilu Akure si le. Aarin Ilu Akure ni
aafin Oba Akure wa. Won si ko aafin naa ni odun 1150AD. Awon aafin kekeke to wa ninu
agbala yi le ni meedogun. Awon bi Ua nla,
Ua Ibura, Ua Jemifohun, Ua ikomo abbl. Oja oba ko jina si aafin oba. Oba Akure
ni anpe ni Deji Akure. Awon Oloye mefa ni won nse amugbalegbe oba won.
Aworan Ekun ni ami
idanimo awon Akure. Oun ni won se nso wi pe "Omo Akure
Oloyemekun". Ni odun 1915 ni awon
ijoba amunisin( colonial masters) da ilu owo, Ondo ati Ekiti po si abe ijoba kan naa. Won si fi Akure se Olu ilu
won.
Oba Adebiyi Adesida lo
ropo Oba Damilare Adeshina ti won ro loye ni ojo kewaa osu kefa odun 2010.
Ilu Akure ni ile ise
telifisonu meji ati ile ise redio meje. Awon ile eko giga to wa ni ilu naa ni:
FUTA, School of Nursing &midwifery ati school of health technology. Lara
awon eeyan pataki ti o ti ilu yi jade ni
Oloye Olu Falae
Oloye Reuben Fasoranti
Philip Emeagwali(won bi ni Akure)
Mama to bi Sunny Ade
Engr. Julius Alabi
Kole Omotosho
Kayode Ajulo
Wow
ReplyDelete