Sunday, 9 October 2016

AKURE



                           
Akure je ilu nla ni ile Yoruba, ni orile ede Naijiria. Oun ni ilu toto bi julo ni ipinle Ondo. Oun si tun ni Olu ilu ipinle Ondo. Awon ti o wa ninu ilu naa je 484798 ni odun 2006. Ni ilu Akure ni awon onimo ijinle Sayensi tiri egungun eniyan to dagbajulo ni gbogbo iwo oorun Afirika. Iwadii so wi pe ojo ori egungun naa je odun to le ni egberun mokanla. Itan so wi pe Omoremi Omoluabi to je

AGO IWOYE



               
Ago iwoye je ilu ni abe ibile ariwa Ijebu ni ipinle Ogun.  O wa lara awon ilu ti ero po julo ni ipinle Ogun. Ilu meje pataki lo wa ni Ago Iwoye. Awon ni Idode, Imere, Isamuro, Ibipe, Imososi, Igan ati Imosu. Oruko oba won ni Oba Abdulrazak Adenugba. Oye Oba won ni Ebumawe ti Ago-Iwoye. Ile eko giga yunifasiti ipinle Ogun wa ni Ago-Iwoye. Won da ile iwe naa sile ni odun 1982.
    Die lara awon eeyan pataki ti o ti. Ilu yi jade ni
- Omoba Segun Adesegun, igbakeji gomina ana ti ipinle Ogun
- Ogbeni Olusola Ogundipe, oga patapata(o ti feyinti) fun awon ajo awon elewon(NPS)
-Seneto Jubril Martins Kuye
-Brigadier Babafemi Ogundipe
Iye awon to ngbe ninu ilu yi le ni 120000

AKUNGBA AKOKO



                 
Akungba akoko je ilu kan ni ipinle Ondo ni Orile ede Naijiria. Ninu ilu yi ni ile eko giga Yunifasiti Adekunle Ajasin wa

AGBAJA



                      
Agbaja ni agbegbe ibi ti won ti nwa irin tutu(iron ore) ni ipinle Kogi. Awon ara Oworo ni o ngbe ni Agbaja.  Agbaja naa ni olu ilu awon Oworo. Ilu yi wa lori oke, ti o sunmo ilu Abuja. Ilu yi ni irin tutu to po lopo yanturu.

ADO EKITI 2



       

 Ado Ekiti je ilu ti won ngbin isu, ege, agbado, oka, tobako ati ewe owu. Iwadi sayensi fi han gbangba wi pe awon eniyan ti ngbe ni Ado Ekiti ni ole ni egberun odun mokanla seyin(11,000 years ago).
      Awon omobibi Ado maa nje akinkanju ati jagunjagun to gboya. Lara awon akikanju won ninu itan ni Ogbigbonihanran ti Idolofin, Ogunmonakan ti Okelaja, Fasawo(Aduloju) ti Udemo ati Eleyinmi Orogirigbona ti Okeyinmi. Itan so wi pe omo iya kan naa ni Oba Ado Ekiti ati Oba Bini. Awon mejeeji je omo Oduduwa. Oye Oba won ni Ewi. Ado Ekiti di Olu ipinle Ekiti ni ojo kinni osu kewaa, 1996 ti won da Ipinle Ekiti sile.

ADO EKITI



               


Ado Ekiti ati Osan Ekiti je  Ilu nla ni ile Yoruba, won tun maa n pee ni Ado. Won to 308,621 eniyan(2006). Won ni ile eko giga yunifasiti ni lu won ti o je ti ijoba, won si ni eyi ti o je ti aladani(Afe Babalola University Ado Ekiti). Won tun ni ile eko giga gbogbonise(Federal Polytechnic, Ado Ekiti) ile ise amohunmaworan meji (NTA Ado Ekiti ati Ekiti State Television) won si ni ile ise redio meji(Redio Ekiti ati Progress FM)

FIDITI



                     




  Ilu Fiditi wa labe ijoba ibile Afijio ni ipinle Oyo. Gege bi akosile eto ikaniyan odun 2006 awon to wa ni ibile yi to 134,173 ni ye. Olu ilu Afijio wa ni Jobele. Woodu(ward) mewaa ni a pin ibile Afijio sii awon ni Ilora 1, Ilora II, Ilora III, Fiditi I, Fiditi II, Aawe I, Aawe II, Akinmorin/Jobele, Iware ati Imini.