Sunday, 3 July 2016

AYEYE ISILE KAN TI WON SE NI ADUGBO MI

                                                               



     Ajanaku koja mori nkan firi, baba rerin ka so pa a rerin ni oro ile awo-ya-nu-wo ti Adajo agba Ajisafe ko si adugbo wa, see won ni olowo see oun gbogbo tan, bii ile naa tiri janran-janran to, osu merin pere ni won fi ko gbogbo re pari lati ipile. Adugbo Bode Eleyele ni Surulere ni ile naa wa.
      Won ra ile ati ile po ni. ni adugbo wa. N se ni awaro wi pe won kan ma a tun ile naa se, ti won si ma kun loda nitori ile naa kii se kekere sugbon oun to yawa lenu nikete tawon to wa ni be ko kuro ni pe ari ti katakata budosa wo adugbo wa, won wa  lo si ojule karun-un won si wo gbo ile alaja kan kale fin-in fin-in.
 
       Lojokeji ni ise ti bere lori ibe ti won si pari gbogbo re ni akoko ti agbasese naa da, ti ise osu merin. Ile yii dabi eyi to sokale latoke orun wa ni. Ewa re ti poju. Agbo wi pe ati ilu oyinbo ni won ti mu awokose ile naa wa. Ile alaja kan ni. Awon oun elo igbalode ni won lo. Ona ti gbalode ni won fii ko. Awon orule ta won tolowo nlo niisinyi  niwon lo.
      Ile to joju ngbese. Enikeni to ba wo ile naa yoo ri nkan meji: ise opolo ati agbara owo. Ko si eni to koja ladugbo wa ti kii fe ya ile naa. Awon eniyan ndiidi wa woo ni.
 Laipe agbo wi pe won fi isile sii ojokejo osu to tele igba ti won pari ile naa. Won mu aso leesi olowo iyebiye. Opa mefa re je egberun lona aadota naira. Eleyii kuro ni  ora ankara o o je semo, o ora leesi o o je semo ni eleyii o. Awon eniyan nla nla ni won ra awon aso naa. Awon bi seneto, awon logaloga, awon agbejoro, awon alenu-looko nilu.
   Gbogbo maalu ti won so mole je marun. Ni ketekete ti inawo ku ola ni awon godogodo soja ti po ni waju ile yii fun aabo, nitori irufe awon eniyan to nbo wa. Awon oko nla nla ni won wa ja oti. Won dii di gbe ise ounje sise yii fun awon toloruko ni bi ise ounje sise ni. Eto ipalemo lo ni perewu.
    Eto isile yii bere ni agogo meta osan. Awon eniyan ti peju pese si enu ona. Awon alufa ijo pelu awon aafa mosalasi ko gbeyin. Awon olori elesin mejeeji niwon gba laaye lati gbadura fun ile naa. Leyin naa olotu eto fito wa leti wi pe eni to maa sile naa ni seneto Oluremi Tinubu.
    Awon eniyan sun seyin ki aya Tinubu le bo sibi ti okun wa. Seneto gbadura ranpe. Won ni: ni oruko olorun baba, olorun omo ati olorun emimimo a sii ile yi fun gbigbe ni alaafia, ki ibukun ati aabo oluwa ko maa wa lori re nigbogbo igba. Leyin naa won ge okun isile naa. Awon eniyan bere si nii ki Adajo Ajisafe ku oriire.
    Awon eniyan wo inu ile. Agbala re teju, o fe. O to o se inawo. Won ti to aga si  be lelegbejegbe. Awon eniyan kan lo joko, awon miiran si n fun ojuu won lo nje. Ile naa ni yara igbalejo merin, yara iwosun lonaa ogun, yara igbanse kookan ni yara kookan ni. Ninu agbala yii, odo adagun igbalode wa ni be.
     Nikete ti gbogbo eniyan ti joko, orisirisi oun ti enu nmu ti wa lori tabili. Won ti wa eran jo sinu awon abo nlaanla lori tabili enikookan. Awon olonje si n lo ba enikookan lati beere nkan ti won fee je. Gbogbo ounje, lo wa. Ko da bee so wi pe e fe ounje oyinbo, e eri ni be. Bee fe tibi le, o wa. Kosi ru eran ti ko si ni be.
    Awon gbajugbaja olorin merin lo sere lojo naa. Oba orin Osupa Saidi lo koko si de orin kiko. O ko boto lorin, awon eniyan naa si yeesi pelu owo, paapaa julo awon to feran ijinle yoruba ati asa wa. Leyin naa Alhaji Sefiu Alao omo oko, naa bo de. Osere awon aye gba ti e naa, won si nawo fun.
    Leyin Sefiu, Kwamu wanu, Oba orin Alhaji Wasiu Ayinde wo le de. Awon eniyan hoo geee. Inu won dun pupo. Asiko naa ni orin Wasiu Ayinde kan sese jade to ko wi pe: eyin mama esenpe. Orin yii lo fi wole. Awon odo fo soke. Gbogbo ijo bere, atewe atagba. Beeni awon eniyan n nawo fun elere lo. Awon eniyan naa si n nawo fun Oloye Ajisafe. Bi won see na wo fun un lohun naa tun na fun awon eniyan.
   Nipari pari re, Oloye Sanni Ade lo kase eto nle. Inu awon agbalagba dun, awon odo lo sempe bayii, ariya di tawon agbalagba. Ijo nlo ran-in, ran-in, awon eniyan na sege owo lojo yi. Ariya pari lagogo merin aaro. Awon eniyan si gba ile lo. Olori adura mi lojo naa ni ki iru oun ire bayii ma gbeyin loro kowa wa.

No comments:

Post a Comment