Friday, 15 July 2016

OLUKO TI MO FERAN JU




       Oruko oluko ti mo feran julo ni Ogbeni Ojuromi Oladele.Won je omo bibi ilu eko.Won si je Olukoni ni le eko girama awon obinrin ti o wa ni  Agege.Lesini irole ti won da sile fun awon akeeko ni a ti pade. Won je olukoni fun imo baoloji. Okan ninu awon oree mi lo mu mi mo ni pa lesini naa. Oruko re ni olajube Ayobami.Oruko ti won npe lesini naa ni gba naa ni mireku tuto.
      Ni ijo ti ogbeni Ojuromi ko wa ni imo baoloji yi, bi eni foyin senu ni. Imo won jinle lori baoloji lopolopo. Mo ti riru tisa bii ti won ojo pe. Olorun oba fi ise naa ro won lorun. Won yato si awon ti won ma nka iwe bi won ba se nko akeko. O ti wa ninu opolo won. Ni ijo ti won koko kowa ni baoloji yi, won beere ibeere kan, wi pe ki enikan dide ki o lo ya seeli eranko si oju patako. Kosi enikokan to dide ninu gbogbo awon to ti wa ni lesini yi tele. Mo  na wo. Won fun mi ni efun, mo si lo ya nkan naa si oju patako.  
      Nigba tii mo yaa tan,won yee wo, won rii wi pe o dara, inu won dun,won si se adura fun mi, wipe Olorun abunkun mi. Won ko wa ni mo baoloji bi wipe akeekoo fun imo isegun oyinbo ni wa. Igbakugba ti won ba ti n ko wa ni won maa nso wipe, ibawu awon ki gbogbowa lofun ise dokita, wipe nibe lati maa mo riri oungbogbo ti awon nko wa.
       To ba tun dori piratika,baba niwon je. Gbogbo nkan ti mo mo loni lori piratika baoloji, awon niwon ko mi. Bi a se gbodo gbe enu pensulu wa ko mu sasa. Bi a o se gbodo kun oun ti a ba ya. Bi ase gbodo fa awon ila ajuwe, fun eya ara awon nkan ti a ya. Bi ase gbodo ko oruko si a be nkan ti a ba ya.Gbogbo re si wa lori mi titi dotun lameta.
       Iru eniyan wo ni ogbeni Oladele nse? Won je eniyan jeje. Won kii soro ju rara. Won je akinkanju eniyan ti o si gba jumo se daradara. Won kii se imele. Won je musulumi ododo to maa n ki irun mararun re dede. Iyawo kan ni won ni pelu awon omo alalalubarika merin-in. Gbogbo wonni won ko nilana olorun, ti won si kawe.
     Nigbatii won finko wayi, won ti ni iwe eri masita won ninu imo awon afomo inu, labe eko ni pa eranko. Nigbatii Olorun maa gbo adura won, won ri ise oludanileko sile eko yunafasiti eko, ti an pe ni lasu. Eleyii ko ya mi le nu tori wipe mo mo iru eni tiwon nse. A ti wo ile eko giga mi ko si se yin won rara.
    Oun kan ti mo mo ni pa won ni wipe won feran awon akekoo to niwa to si mo we. Sugbon bi akekoo kan ba wa, to ni oun yi lori, awon naa mo bi atii fowo lile mu iru won. Won korira afojudi. Bi akeko kan ba huwa afojudi si won yoo je iyan re nisu.
     Gegebi eso ati apeere ipa ti won sa lori awa akekoo won, ise ti wonka nile iwe giga le mi naa lo fun. Ile iwe giga ti won lo, le mi naa nwaye si. Ise ti won nse, lemi naa pinu lati yan laayo bi moba setan. Olorun to mu ki Ogbeni Oladele ojuromi yan, tan yanju yoo ti e mi naa leyin lati yan, ki n si yanju.

2 comments: