Rogbodiyan
akekoo to sele loju mi sele ni iwaju ile iwe giga ti LASU ni odun 2002. O wa ye
laarin omobinrin akekoo ile iwe lasu kan ati ogbeni soja kan. Won jo wo oko
akero kosta lati mile 2, nigba tii omoobinrin yii fee bo sile, o se si lati te
ogbeni soja yii mole, laimo nigba tii soja so fun un, oni oun ko moo mo soja si
fun ni igbati olooyi, omobinrin yi ko se
mini semeji o bu soja yi so ninu oko, se won de ti de iwaju ile-iwe won.
Awon omokunrin
ti won wa ninu moto ton je omo LASU dasii, won ni ki soja naa bo sile niwaju
lasu,o ko lati bo sile, o fe e ba won sagidi, sugbon won fi tipatipa woo bo
sile. Won saa lefa se, soja subu. Won woo wonu ogba ile iwe won, won si fi
ajeku iya jee ki won too fi sile.
Nigba tii yoo
fi di bi iseju ogun. Awon godogodo de. Oun naa ti lo si bareke won lati lo fejo
sun, awon egbe re si sigun wole. Oro wa dibo o lo,oyaa mi, awon soja ti de, se
ni won nlu akekoo kakekoo ti won ba ri.
Iroyin ti kan
awon asoju awon akekoo ninu ogba. Won si jade biba awon naa dojuko awon soja
pelu oko, won nso won loko. Awon to laya akeboje ninu won sunmo awon soja to
gbe bon dani won nba won ja lai bikita pe ibon wa lowo soja. Bee lawon soja nyibon
soke ki won le seruba awon omo ile iwe, gbogbo re wadi rogbodiyan.
Wahala naa lo
ni ronto fun bii wakati meji. Nigba to ya awon soja ko awon asaju awon akekoo
sinu oko won, won gbe won lo si bareke won. Nse ni awon akekoo ro tele moto
won. Won ro ra won di oju titi ba mu, won fe se rinlo, lati lo gba awon olori
won ni bareke awon soja, won si da sunkere fakere oko pupo sile ni ojo taa n wi
yi. Aseyin wa, aseyinbo won da awon asoju awon akekoo sile leyin ti won ti jo
ni ajosopo oro tan ni bareke won. Iye awon ti won fara pa ninu awon akekoo lojo
naa le ni aadota. Meji ninu oko awon soja niwon dana sun siwaju ogba ile iwe
naa lojo naa, ti soja marun naa si farapa yanna yanaa. Rogbodiyan ki ibimo to
ro. Suuru loso ngbo gbo.
E kare egbon mi atata...
ReplyDeletealfa sawlew ba wo ni gbogbo nkan ati awon ebi mi loun, o see gan
ReplyDelete