Faari
je oun ti a le pe ni ako sise, to je asa to wopo laarin awon odo ati
agunbaniro. Otun yato si oge sise, bakan naa won si wonnu ara won. O je asa
olaju ti awon odo maa n fe ko. Faari je asa ti o ma n farahan ninu ihuwasi, oro
siso, ara mimu, irinrinrin, lilo eya ara kan lona to tun yato. Opolopo igba
nifaari maa nje asa ti a ko wole nipa wiwo awokose awon ti a ro wipe won laju
juwa lo
Faari je ona kan ti odo langba fin fe ki awon
eniyan mo wipe oun wa nile. Won fe fi han wipe asiko awon yutu re. Bi a ba so
wipe eniyan gbo faari iyen ni wipe eni naa mo pepe furu se, eni naa feran ati
maa lo nkan igbalode, osi feran ati ma ko asa igbalode, tabi dasa igbalode.
Yoruba bo won ni igba ara lan bura enikan ki ibu sango leerun. Ko see see lati
so pe ki ewe ti ojuure bati la si faari sise ma see, sugbon oun ti o se Pataki
lati mo ni wipe iwon-tun – won-si ni leke ogbon eni bi ologbe Sikiru Ayinde se
ko morin re.
Ti
eniyan yoo ba se faari ko ma se faari
gbemi-gbemi tabi eleyii to nso ni daabo ara lojo iwaju,ko gbodo je eleyii ti
atunbotan re koni dara lojo iwaju. Faari aseju a maa ko bani bi apeere awujo wa
je awujo to gbe asa omoluabi laruge. lara abuda omoluabi si ni iwon tun wonsi
wa. Bi faari omo birin ba poju, oju alasewo ni awon eniyan mama fi woo lopo
igba. Bi i keniyan to oju, imu,ereke, ko luti bi ona merin, ko wooso ko maa fi
ihoho re han je awon asa ti Yoruba ki i fi oju eniyan tonilaari wo won a si ri
iru eniyan be bi eniti ko ti ile ire jade.
Atunbotan buburu miiran to tun wa ninu faari aseju ni wi pe ni opolopo
igba kii so eso rere fun ilera eni to nse iru re leyin wa ola. Bi apeere eni to
lo bora ni tori faari si se, nigbato baya ti ara ba n da ra agba, awon isoro
ilera kookan ama jeyo. Bi won ba fee se ise abe fun won yoo di isooro tori ara won le soro lati ran. Iru won
ni o maa nsagbako arun jejere ti ara. Orisirisi awon kemika ti won lo ni gba
ewe maa n lo sa pa mo si ara lati je jade lojo ale.
Atunbotan bururu miran ti faari aseju maa n mu
wa ni wipe, bi asa ba ti di baraku fun ara, kii se gbaboro. Bi apeere odomokunrin
to n rin to ndegbe rin lai jepe ese ndun won, ti won nfi sako rin, ti won ntiro
ese rin lati fi se faari, nigba to baya iru irin bee ko ni ye ojo ori won mo,
ti won ba fee wa se atunse koni wa rorun mo lati se. Ara won atidi eja gbigbe
ti ko see ka mo.
Idimiran ti faari aseju ko fi dara ni wipe
ofin awon iwe mimo mejeeji kofaye gba aseju.iwontun iwonsi ni awon lemonu
mosalasi nki gbe beeni iwe peteru so wipe ki obinrin je kii ewa oun je ti iwa
tutu ati okan to dake je. Oti le so wipe ki a ma se jekii ewa wa duro lori awon
oun eso ati aso olowo iyebiye ti ale fo juri.
Faari
aseju le je ki won mu odomokunrin fun
ole ni gba tii olopaa koba le so iyato laarin imura re ati ti awon igara olosa
ti won nwa. Omobinrin ti dokita oju ko fun ni igo oju to nkan go moju kaakiri
bope boya oju amaa wo baibai.
Faari aseju kii bi mo gidi eje ka se oun
gbogbo leso leso.
No comments:
Post a Comment