Oruko ore ti mo feran julo ni Tope Adesiyun.
O je omo bibi ilu Akure. Omo idile oba ni ise. O je eniyan giga. Orewa
lokunrin. O mo oro so. Olorun si jogun ogbon fun. O loyaya, ara re si yomoyan. Pabanbari
re ni wi pe o je eniyan ti o ni feran olorun ti o si beru olorun tinutinu re.
Olooto eniyan ni. O feran nkan ti emi.
A pade ara wa ni odun egbaawa ole meje ni
osu kokanla, ni ilu Kaduna, ni ibile Sanga. Ilu kan naa ni won pin wa si fun
ise agunbaniro. Ise tisa si ni won fun awa mejeeji lati se, ile iwe girama ti o
wa ni abule Gbonkoki ni won gbe emi lo, ti won si gbe oun lo si ile eko girama to wa ni
Fadan Karisi, sugbon gbogbo wa maa n pade ni eekan losu ni Guwontu fun ipade
olosoosu awon kopa.
Ninu egbe awon Kopa onigbagbo ni a ti
pade. O wulo fun ise egbe naa, bi emi naa se wulo fun egbe naa. Nijo kan, leyin
ipade awon kopa ni o so wipe oun yoo ba mi dele mi loni lati wa mo ile mi.
Nigba tii ajo dele, a foro jomitoro oro lorisirisi. Ajiroro bojo iwaju waa se
maa dara. Nibiyii ni ore wa ti bere.
Nigbatii
a lo se danwo NIM ni ilu joosi, ti a ko moo eniyan si, Tope ni o setoo fun ibi
ti agbe. Bi o sesee, nko mo, sugbon awon eniyan naa se tojuu wa daradara. Ti a
ba fidida temi nikan ni, boya oju titi ni nba sun, tori nko lagbaja nkan bee
rara.
Oun kan pataki ti o mu mi gbaa gege bi
ore ti mo feran julo ni wi pe o huwa kan si mi, ni eyi to ku die kia se tan,
eleyii ti emi ko ro pe o ye ko ri be, o dun mi, mo si pinu lati yera fun sugbon
bi mo ti yera fun un to, ko fi mi sile, o wa mi kan, nigba tii a fi Kaduna
sile. O gbera lati Akure o wa mi wa si Eko. Eleyii jo mi loju pupo. Wi pe ko wo
ti iwa aibikita ti emi naa wu si, ko je ki okun ore aarin wa ja.
Mo wa rii wi pe o je eniyan ti o ni okan
agba, o simi iwa idariji ati ti irele. Lati igba naa ako je ki enikeni ko
raarin wa mo. Opolopo ona ni a ti gba wulo fun ara. Ni opolopo igba ti mo ba
fee se ipinu lori nkan, ti nkan naa si ru mi loju, bi mo ba ti pee taa foro
jomitoro oro lori nkan naa, olorun yoo lo lati tan imole si ona mi lori nkan
naa.
Ni ojo igbeyawo mi oun ni o se ore oko
fun mi. Ni ojo igbeyawo ti re naa, emi ni mo se ore oko fun oun naa. Ise Oluso
Agutan loo nse, nigbatii mo si yan ise olukoni laayo.
Very interesting
ReplyDeleteFantabulous I even used it for my assignment
ReplyDeleteMe too
DeleteWow interesting
DeleteThis is very helpful I even used it for my assignment
ReplyDeleteThis is really useful to practice my exam
ReplyDeleteYou really tried i wish to reward you
ReplyDeleteVery useful
ReplyDeleteI practice it for exam
Wow, you really tried
ReplyDeleteBravo
ReplyDeleteU tried a lot