Saturday, 16 July 2016

OLUSEGUN OBASANJO




      Oloye  Olusegun Obasanjo ti a bi ni ojo karun osu keta odun 1937, je ogagun soja to ti fe yinti. Won si je olori orile ede Naijiria lati odun 1999 titi di odun 2007.  Won  je omo bibi ile Yoruba. Ise soja ni ise ti won se, ki won too wa se olori orile ede won lee meji. Lakoko gege bi olori  ijoba ologun lati ojo ketala osu keji odun 1976 di ojo kinni osu kewa odun 1979. Lele keji, gegebi are orile ede
ninu ijoba awa-arawa lati ojo kookan -dilogbon osu karun odun 1999 titi di ojo kookandinlogbon osu karun odun 2007. Lati osu keje odun 2004 titi di osu kini odun 2006, oloye Obasanjo ni won se alaga ajo fun isokan awon orile ede Afirika

.
     Won fidi kale si Abeokuta, ti i se olu ilu ipinle Ogun, won gbe igbe omoluabi. Won si je oye Balogun Owu, awon naa ni ekerin Balogun Egba ni ile Yoruba.
     Abi Oloye Obasanjo si ipinle oogun, won  si da gba si Owu, Abeokuta. Oruko iyawo won akoko ni Oluremi, Obinrin yi ni o bi awon to dagbaju ninu awon omo Obasanjo, eyi to je ilu mooka julo ninu awon omo won  ni Dokita Iyabo Obasanjo Bello, to fi gba kan je asofin fun orile ede Naijiria, lati ipinle oogun.
     Ni odun, 1987, e yi ti o je iyawo won keji,  ti won ti ko sile, ti oruko re sinje Linda, ni awon ti won di hamora ogun pase fun ki o bo sile ninu oko re, ibon ti won yin fun si se lese lopo nitori ko tete boole. Ni ojo keta-le-logun, osu kewaa odun 2005, Are padanu iyawo won tii se Stella Obasanjo, ti o je obinrin akoko fun orile ede ni gba naa, leyin ti o se ise abe fun ikun re ni ilu Spain. Ni odun 2009, ile ejo da dokita to se ise abe fun stella lejo,won fun ni ewon odun kan fun iwa aibikita re, won si pase fun un ki osan iye dola 176,000 fun omo re okunrin.

     Oloye Obasanjo ni omo topo,won ngbe kaa kiri orile ede agbaye. Omo won, Dare Obasanjo je manija ni ile ise Microsoft. Ni omo odun mokanlelogun ni Olooye dara pomo ise ologun ni odun 1958. Won lofin idani leko olosu mefa ni ilu England ki a towa so won di ofisa ninu ise ologun. Won tun loko eko ni ilu india ni pa ise ologun.
    Nigbatii Oloye Olusegun Obasanjo je Are, awon naa naa niwon se minisita fun epo robi fun ra won odun 1979. Won gbe joba sile fun Shehu Shagari ti a dibo yan gege bi are fun ijoba awarawa. Awon ni Are ologun akoko to ma gbe ijoba kale woorowo fun ijoba awarawa ni orile ede yii.
     Ni igba aye ogagun Sanni Abacha (1993-1998). Oloye Obasanjo soro lodi si awon iwa fifi eto omo niyan dun ni, to sele nigba naa eleyii mu ki Abacha fi  won sewon pelu esun wipe won wa lara awon to fe fi pa gba joba lowo oun. Igba ti Sani Abacha ku ni ojo kejo osu kefa, odun 1998 ni ato tu Oloye Obasanjo sile. Ninu ogba ewon ni won ti di atunbi onigbagbo.

     Leyin ti won fi ori aleefa sile, awon ni ose alaaga igbimo awon agba egbe PDP. Funra won ni won si fi ipo yi sile ni osu kerin odun 2012. Leyin re won jawo ninu oselu. Won je okan ninu omo egbe Club de Madrid, ti iye awon omo egbe naa leni ogorun. Awon ni egbe awon Are ana ti won se Are fun ijoba awarawa lori le ede won.

No comments:

Post a Comment