ORIKI
AWON IJEBU
E e e e e e
e e e e
Awa niyin
eeyan, awon ode omo digbolugi
Awon niwon
maa nso pe ijebu oloriki
Iro
patapata niwon npa, eyin ijebu momo oriki baba teyin
Wonni boba wun jebu awun ni e ni winiwini
Bo ba wun
jebu awun ni e ni winiwini
E e mope
boba wun jebu afenire yooku sodun agemo.
Won okuku
mekun wo gbosara ri
Iba lomekun wo gboremo
Eyin lomo
afinju jebu tii foko ree japena.
Omadunrun
made o, nle madunrun mosuu medieyege
Omaa ladie,
ogogo moja
Eleyi tii
le yeye bi a wo tiigbin tiigbin.
Omadie
borogun, bogoolele
Ara orokun,
ara ora die
Omo hun –
un seni oyoyo nyo.
Oyoyo
mayomo,un tin seni o lee pani
Omo dudule,omo
be e se njosi
Pupa tomo
bee se okuku sinle
Omo moreye
maa maa roko
Moroko tan
eye siitilo
Omo moni su
nle mi o lo be
Obe tii be
leye, omo le baba tobi won lomo
Loni mori
gba lodo baba tawon
Ome nile
made, o mo onile mawo mawo
Omo onile
kan ajoji won o gbodo wo
Ajoji toba
wo gboooro, yoo de ni e bora nile
Baba tobi won
lomo
Ijebu omo
eere niwa.
Omo olowo
sembaye, kowo kukusi to gbode
Koto dowo
eru, koto dowo omo
Iran ijebu
nina wo dollar ko oyinbo togbowode
Oyinbo
gbowode lowo oun posi
Omo
elekunje ajowiire
O osa
jendabi onileyi
Ni won se
nwipe
Igbe jebu
owo,ito jebu owo
Kekere jebu
owo, agba jebu owo
Dudu jebu
owo, pupa jebu owo
Kukuru jebu
owo, giga jebu owo
Gbogbo jebu
timo mo niwon lowo lowo o
Ijebu nle
omo abere ni wa.
(Baba
Ajobiewe lo fi kewi, kin to koo sile)
No comments:
Post a Comment