Ise
loogun ise
Mura
sise ore e mi
Ise
la fi n de ni giga
Bi
ako ba re mi feyinti
Bi o
le laari, bi ako ba re ni gbekele
Atera
mo se e ni,
Iya
re le lowo lowo,
Bo
ba gboju le won
O te
tan ni mo wi fun e
O un
ti a ko ba jiya fun
Se kii
lee tojo
Oun
taa ba fara sise fun
Niipe
lowo e ni
Apa
lara, igunpa ni ye kan
Bi a
ye fe o loni, boo ba lowo lowo
Ni
won ma fe o lola
Eko
situn nsoni doga
Mura
ki o ko tire daradara
Iya
nbe fomo ti ko gbon
Ekun
nbe fomo tin sa kiri
Ma fowuro
sere ore mi
Mura
si ise ojo nlo.
Ise
je oun ti eniyan yan lati fi okun, agbara ati akoko re se ni reti wipe yoo mu
owo wa fun ni tabi mu ere wa fun ni.
Eredi akoko ti a fi nsise ni lati lowo lowo fun anfani ara eni ati itoju ebi
ati ara.
Nse ni ama n se ise. Eniti oun sise lo si
maa nreti ere. Ise je oun ti ase lati mu ki aye rorun fun elo miran. Ti i se ti
eniyan ba se ba wulo fun elomiran ni a le
reti ere nibe tabi owo ise.
Ise ni o di won. Oun ti a fin se odiwon ise
ni iwulo tabi anfani ise, ekun ise, tabi akoko ti a lo lori ise naa.
Orisirisi ise lo wa. Okan ninu won ni katakara.
Irufe eniyan bayii yoo woo oun ti awon
eniyan nilo, tiwon le kowo lori lati ra. Yoo lo ra nibi ti won tin se tabi lodo
awon asoju awon tiwon nse e. ki o le rii ra ni edinwo. Toba de awa siro laalaa re,
owo oko, owo iso oja ati iye ere ti oun
reti lee lori. Iyen ni yoo taa. Bi awon
eniyan ba si se nra oja naa ni ere re yoo maa posi.
Orisi ise miiran ni ise owo. Eleyii ni ise
ti eniyan ko.Eni naa yoo ti ko ise naa yanju lodo oga re.Oun naa yoo maa se ise
yi ni ayika awon ti won nilo irufe ise bee. Apeere ise owo bee ni ise onidiri,
ise alagbede, ise jorinjorin, ise
kolekole, ise gbenagbena, ise onilu, ise akope, ise ounje tita, ise erantita, ise foonu titun se ati bee bee lo. Gege bi
apeere bi moto ba ba je ti won sigbee wa si odo mokaliiki, ti o batun se tan, yoo gba owo gba owo ise lowo
eni to ni oko naa.Owo ise ti o ni se owo bagba je ajemonu tire.
Orisi ise keta to tun wa ni ise olopolo, ise
afopolo se.Eleyii le ma ni irinse ti a fojuri ni opolopo igba, apeere awon ise
ti ale ri ni abala yi ni ise olukoni, ise agbejoro, ise adajo, ise oloselu, ise
sorosoro, ise dokita, ise olorin, ise ijo jijo, ise lemomu, ise oluso agutan,
ise olugbani-ni-moran ati bee bee lo.
Se osise lokuku jare ise. Ise to semo logun
odun, iya to jomo logbon osu, bi ko ba pa omo, agbe omo naa.Ayo nii pani ise
kii pa niyan.Yoruba bo won ni bori ba pe ni le aadire. Won ni ape
koto jeun kii je baje. Bi eniyan kan ba wa ti ko fe ise se, ole la ape iru won.
Won si maa n koo lorin wipe ole lapa kole sise, ole faso iya bora sun.
Ni ile kaaro oojire, ise sise wa lara abuda
omoluabi. Eni to ba feran ise sise laa npe ni akinkanju eniyan. Eni toba sise
pelu ori pipe lo maa nlowo.Eni to ba faro sise ni yo ni igbadun losan ti yoo si
sinmi lojo ale re. akii fun oni mele eniyan lobirin fe nitori koni roun bo o.
onimele eniyan lo maa ndi alafowora, ole, gbewiri tabi olosa, tabi adingunjale.
Yoruba bo wonni owo to ba dile lesu n wa se
fun. Beeyan kan wa ti kii sise iru won niirin ni bebe oun olohun. Kosi bo ti wu
ko buru to ti eniyan koni rise se laye. O le nikan laaye o gba, ibi gbogbo lo
gbalagbara. Kosi bi ilu sele leto ti eniyan kan o fi ni rise se, teeyan ko ba
ti sako, ise polo sua.
Orisirisi ise lowa taaba tibi ere woo. Awon
ise kanwa toje wipe ati je atimu nikan ni won ka. Gbogbo ere to njade lorire
koju oun ton ngbo jije ati mimu nikan. Iru ise eleyii ko faaye ajeseku pupo
sile tabi ko ma si rara. Iru awon wonyii ni won nsise bi erin to won nje je
eliri. Opolopo ise to wa lode lowa labe eleyii. Sugbon ibi kan saa leeyan ti nbere
nkan. Beeyan ba bere pelu ise kekere to gbaju moo, ti ko naa ina apa, to si ngbadura, bope boya, oun ti ko to sii nbo wa
seku.
Ise keji to wa ni eleyii ta n pe ni ise
alalubarika. Ise to see fi yangan.ise to ni ere pupo ninu. Ise taafi se nkan
ire laye. Lara awon nkan too nmu eniyan rise alalubarika ni bi eniyan base ise
ti eleda re yan laayo fun. Ori wa oni je ka sise oni se o, beeyan bawa ise tori
yan fun, to si joko ti iru won kii pe laye. moke,,iru won. Beeniyan kan bawa t’eledaare
fe ko maa yan guguru ta, teni naa wa n
sise banki, ko le moke, o le ma la kojo. Kole sorire to maa kale, iru won kii
ni fokanbale.
Eyi to poju ninu isoro ise sise ni egbe awon
to n sise onise wa. Oun losii faa ti ise ati iya fi ipo ni awujo wa. Awon
eniyan ko saapon lati mo pato ise tori yan won
Oun to ti dara julo nipe ki eniyan ti mo ise
toro mo eledaa re. bi oni toun ba timo eyi to n see, ton te pamo,to fi gbogbo
okankan see, ti ko fi mele see, ti ko fi
gbakan bokan ninu, bo ti wu kope to, yoo la nibe ni.
Iru apeere yi ni ti Aburahamu linkonu ti ise
olori orile ede ilu Amerika nigba kan ri. Itan so fun wa wipe opolopo igba lofi
gbe apoti lati se asoju fun orile ede re, sugbon ti o fidi remi ni ipinle re,
sugbon ko je ko su oun. Nigba to tun ya ogbi yanju lati je olori orile ede fun
opo igba sugbon ofidi re mi, sugbon ko je ko su oun, leyin-o-reyin o di olori
orile ede gbeyingbeyin.
Gegebi ewi ti mo ko saaju bi ako ba re ni
feyinti, ka tera mose e ni. Kosi awijare fun enikeni lati wa ninu ise sibe.
Atelewo eni ki tan ni je. Mura sise ore e mi, ise lafi n de ni giga.
No comments:
Post a Comment