Friday 12 August 2016

OGUN ILARA( BATTLE OF ENVY)




     Yoruba bo wonni iwo abanije, ojo to o ba dekun ati bani je, ojo naa la o ba o je. Mo ranti oro kan to sele si mi ni opo odun seyin ni gba ti mo wa nile iwe girama. Okan ninu awon ore e mi ni oro naa towo re sele. Nigba tii a de odun karun lenu eko, ore mi timo timo so fun mi wi pe oun ni oro kan ti oun fe je wo fun mi. emi ni kan ko ni mo wa ni be,ore mi kan naa wa legbe mi.
     O so wi pe nigba tii awa ni kilaasi ikini, ikeji ati ikeeta nile iwe yi, oun wa lara awon ti oluko kilaasi wa maa n pe lati wa ba oun se akosile maaki wa sinu kaadi idanwo wa. O jewo wi pe oun ati enikeji oun maa ndin gbogbo maaki ti mo ba ti gbaku, wi pe, awon o ni je kin gba ipo kinni. Nitori wi pe won mo wipe awon o le gba ipo kinni, bee awon o ni je ki ngba ipo yi.
     Sibe pelu gbogbo nkan ti won maa n se yi, ipo mi ni kilaasi naa ko din ni ipo keta rii. Iyen ni wi pe awon ton gba ipo kinni ati ikeji, kii se ipowon, ipo onipo ni.Sugbon bi won ti se binu ori to yi, won o rii se. Ise oluwa ni ko se ni to ye. Ko seni to le fowo bogo orun.
     Igba tii mo gbo aya mi ja, erubami, sugbon ki ni mo maa se. Ti ko ba so fun mi nko, ki ni mo fe bolorun fa? Nitori naa ni mo se dari jii.
  

Eku  amojuba  apa keji itan iriri aye e mi : ABANIJE

No comments:

Post a Comment