Friday 18 November 2016

Mofimu




Mofimu ni ege  tabi fonran ti o kere julo ti  o ni itumo ati ise ti o n se ninu ede girama
Ti a ba for mofimu si we we ko le  ni itumo.
Orisi mofiimu
1. Mofiimu ipile/adaduro
2. Mofiimu afarahe

ORO AYALO




Oro ayalo ni oro ti a mu lati inu ede miiran wo inu ede kan lona ti bi a ti nko ati bi a ti npe yoo fi se regi pelu ede ti a ti fe loo.
 Lara awon ede ti Yoruba ti ya oro lo ni ede Geesi, Hausa, Larubawa, Faranse ati bee bee lo

ORISI ORO AYALO

AWON OBA TI WON TI JE NI ILE IFE





 ODUDUWA
 OSANGANGAN OBAMAKIN
 OGUN
 OBALUFONO GBOGBODIRIN
 OBALUFON ALAYEMORE
 ORANMIYAN
 AYETISE
 LAJAMISAN
 LAJODOOGUN

AWON OLOWU TI OWU( past and present Owu Kings)





Oba Pawu 1855-1867
Oba Adefowote 1867-1872
Oba Aderinmoye 1873-1890
Oba Adepegba 1893-1905
Oba Owokokade 1906-1918
Oba Dosunmu 1918-1924
Oba Adesina 1924-1936

AWON OBA ILU OYO




Ajaka 
Sango 
Ajaja 
Aganju
Kori
Oluaso
Onigbogi-.
Ofiran     -oun ni o ko ilu Shaki

Friday 4 November 2016

SAGAMU



                                                    
Sagamu je ilu nla ni ipinle Ogun. O si je Olu ilu fun ibile Sagamu. Ilu yi wa ni itosi odo ibu. Ilu yi ni opolopo okuta ti won fin se simenti (limestone), eyi ti won nlo ni opolopo ile ise. Ilu Sagamu ni ibi ti won nko obi(kolanut) to poju lo ni orile ede Naijiria. Ilu yi wa laarin ilu eko ati ilu Ibadan. Ni be ni ile ekose isegun

ABEOKUTA



                                                      
Abeokuta ni ilu ti o tobi julo ni ipinle Ogun. Ilu yi fidikale si apa ila oorun odo Ogun. Lara awon oun ti a le ri ra loja won ni epo pupa, igi gedu, roba, isu, iresi, agbado, owu, ori ati bee be lo. Idi ti won fi n pe e ni Abeokuta ni wi pe abe ori oke Olumo ni ilu naa wa.
Oju ona reluwe wa, ti o lo lati Eko si Abeokuta, o si je kilomita merindinlogorin(77). Won se oju ona reluwe yi ni 1899. Awon ona miiran ti o tun wo Abeokuta ni Ibadan, Ilaro, Sagamu, Iseyin ati Ketou.
    Sodeke ni o te ilu Abeokuta do ni 1825. Gege bi ibi aabo lowo awon olowo eru lati Dahomey ati Ibadan. Awon ara Egba ni won koko tedo si Abeokuta.

AWON OBA TO TI JE NI EKO (KINGS OF LAGOS)



                                         


Ado (1630-1669)
Gabaro (1669-1704)
Akinsemoyin(1704-1749)
Eletu kekere(1749
Ologun kutere(1749-1775)
Adele Ajosun (1775-1780)
Eshilogun (1821-1829)

Sunday 9 October 2016

AKURE



                           
Akure je ilu nla ni ile Yoruba, ni orile ede Naijiria. Oun ni ilu toto bi julo ni ipinle Ondo. Oun si tun ni Olu ilu ipinle Ondo. Awon ti o wa ninu ilu naa je 484798 ni odun 2006. Ni ilu Akure ni awon onimo ijinle Sayensi tiri egungun eniyan to dagbajulo ni gbogbo iwo oorun Afirika. Iwadii so wi pe ojo ori egungun naa je odun to le ni egberun mokanla. Itan so wi pe Omoremi Omoluabi to je

AGO IWOYE



               
Ago iwoye je ilu ni abe ibile ariwa Ijebu ni ipinle Ogun.  O wa lara awon ilu ti ero po julo ni ipinle Ogun. Ilu meje pataki lo wa ni Ago Iwoye. Awon ni Idode, Imere, Isamuro, Ibipe, Imososi, Igan ati Imosu. Oruko oba won ni Oba Abdulrazak Adenugba. Oye Oba won ni Ebumawe ti Ago-Iwoye. Ile eko giga yunifasiti ipinle Ogun wa ni Ago-Iwoye. Won da ile iwe naa sile ni odun 1982.
    Die lara awon eeyan pataki ti o ti. Ilu yi jade ni
- Omoba Segun Adesegun, igbakeji gomina ana ti ipinle Ogun
- Ogbeni Olusola Ogundipe, oga patapata(o ti feyinti) fun awon ajo awon elewon(NPS)
-Seneto Jubril Martins Kuye
-Brigadier Babafemi Ogundipe
Iye awon to ngbe ninu ilu yi le ni 120000

AKUNGBA AKOKO



                 
Akungba akoko je ilu kan ni ipinle Ondo ni Orile ede Naijiria. Ninu ilu yi ni ile eko giga Yunifasiti Adekunle Ajasin wa

AGBAJA



                      
Agbaja ni agbegbe ibi ti won ti nwa irin tutu(iron ore) ni ipinle Kogi. Awon ara Oworo ni o ngbe ni Agbaja.  Agbaja naa ni olu ilu awon Oworo. Ilu yi wa lori oke, ti o sunmo ilu Abuja. Ilu yi ni irin tutu to po lopo yanturu.

ADO EKITI 2



       

 Ado Ekiti je ilu ti won ngbin isu, ege, agbado, oka, tobako ati ewe owu. Iwadi sayensi fi han gbangba wi pe awon eniyan ti ngbe ni Ado Ekiti ni ole ni egberun odun mokanla seyin(11,000 years ago).
      Awon omobibi Ado maa nje akinkanju ati jagunjagun to gboya. Lara awon akikanju won ninu itan ni Ogbigbonihanran ti Idolofin, Ogunmonakan ti Okelaja, Fasawo(Aduloju) ti Udemo ati Eleyinmi Orogirigbona ti Okeyinmi. Itan so wi pe omo iya kan naa ni Oba Ado Ekiti ati Oba Bini. Awon mejeeji je omo Oduduwa. Oye Oba won ni Ewi. Ado Ekiti di Olu ipinle Ekiti ni ojo kinni osu kewaa, 1996 ti won da Ipinle Ekiti sile.

ADO EKITI



               


Ado Ekiti ati Osan Ekiti je  Ilu nla ni ile Yoruba, won tun maa n pee ni Ado. Won to 308,621 eniyan(2006). Won ni ile eko giga yunifasiti ni lu won ti o je ti ijoba, won si ni eyi ti o je ti aladani(Afe Babalola University Ado Ekiti). Won tun ni ile eko giga gbogbonise(Federal Polytechnic, Ado Ekiti) ile ise amohunmaworan meji (NTA Ado Ekiti ati Ekiti State Television) won si ni ile ise redio meji(Redio Ekiti ati Progress FM)