Tuesday 30 August 2016

TOLOTOLO MO ENI TO NYIBON IDI SI




       Oje ede Yoruba ta n lo lati salaye wi pe onikaluku lo mo iru eniyan to le dojuko lati se nkan maje-aye-o-gbo si lowo. Bi apeere o see se ki owo da eniyan, kii se gbogbo eniyan la le dojuko lati basiri wa tabi lati yawa lowo. Iru eniyan ta a le se nkan basiri si lowo ni a yibon idi si.
     The turkey knows whom to direct its fart to.

OLOJUKAN KI I TAKITI ORO




     An lo gbolohun yi lati kilo fun eniyan wi pe eniyan ki i se oun to ju agbara re lo. Nitori alaaso kan kii sere eti omi. Bi apeere iya agbalagba to lomo kan soso laye, ti ko si si oko mo, to ti koja nkan osu sise, ko gbodo so wi pe ki omokunrin kan soso tohun bi mura oju ogun lati lo ja fun iluwon.
    A one – eyed person does not attempt standing somer saults.

Sunday 21 August 2016

GBOLOHUN ONIBO





Gbolohun onibo je iru gbolohun ti a fi bo inu gbolohun miiran.
                        Bi apeere
1.                                                Tolu ti lo le “ki won to sowon   
                        “Ki won to so won je gbolohun onibo
2.                                                Ina ti de ka to jade.
            “ka to jade”  je gbolohun onibo
3.                                                Titi so “pe Segun  ti de”
                 “Pe Segun ti de” je gbolohun onibo.

URHOBO –ISOKO




     Urhobo ati Isoko je ede meji to wa ninu ebi kan naa, won si sunmo ara.Awon ede mejeeji ni o ni bibeli ati  iwe orin won. Baka naa won ni awon iwe litireso orisirisi. Dikisonari wa ni ede Urhobo. Ede Okpe, Urhobo ati Uvwie je awon ede ti o yato meta ti awon eya kan ti an pe ni Urhobo maa nso ni ipinle Delta, ni guusu orile ede Naijiria. Asa kan naa ni gbogbo Urhobo ni sugbon ni ti  eto oselu, idi igi merinlelogun ni won pin si. Ilu meji lo nso Uvwie. Ilu kan lo nso Okpe (awon ni won si poju niye). Ede Urhobo ni awon ilu mokanlelogun to ku n so.
     Ilana ede Agbarho ni awon ilu merinlelogun naa fi nko ede won sile. Adalu ede oyinbo(pidgin) ti ropo pupo pelu ede Urhobo nitori naa awon ojogbon woo wi pe ti won ko ba wa ba nkan se, ede naa (Urhobo) le d'oun igbagbe.

IBIBIO




     Awon ara Ibibio wa lati guusu-ila oorun(south east) orile ede Naijiria. Won tan mo awon Anaang, Efik ati awon Igbo. Ipinle Akwa ibom ni won posi julo.Nitori wi pe awon Ibibio po, awon ni won dari eto oselu ipinle Akwa ibom julo, sugbon won maa npin ijoba pelu awon Anaang, Eket ati Oron. Ki orile ede Naijiria to parapo di orile ede ni awon Ibibio ti ni eto ijoba ara won. Nitori wi pe ipinle Akwa ibom sunmo orile ede Cameroun, awon apakan Ibibio, Efik ati Anaang wa ni Naijiria, awon kan si wa ni Cameroun. Ise epo sise ni ise won tori awon igi ope to po nibe.
      Loni, eyi to poju ninu awon Ibibio je onigbagbo. Mary Slessor lo dekun asa pipa awon ibeji laarin awon Ibibio, nitori eleyii je asa won tele. Won maa ngbe iru awon ibeji bee lo si iru igbo buburu fun won lati ku danu. Eya mefa ni Ibibio pin si.