Friday 16 September 2016

AWON EGBE ONIMOTO (3)




     Apeere awon eto eko ti won le se agbateru re po, to si lapeere. Bii idije ifagagbaga laarin awon akekoo ni ibile kookan (inter school quiz competition) awon omo to ba gbegba oroke le gba eto eko ofe lowo won(scholarship).
     Awon alase won gan le pase nkan bayii fun awon alaga won lati se, ki won si
     Apeere oun miran ti mo tun ri wi pe won file wulo fun eto eko ni sisi awon yara ibi ikawe (library) loruko won si agbegbe won. Nipa si se irufe awon nkan bayii, awon ara ilu a ye foju buruku wo won. Awon naa yoo nipa rere ti won nko lawujo won.
     Opolopo igba ni awon ara ilu ati awon sorosoro tipe wi pe ki won wo gi le egbe naa, ijoba gomina Fasola tile gbiyanju lati se bee sugbon won ko rii se. kole rorun lati wo gi le egbe naa nitori wi pe ofin lo gbe e kale. Eto  ofin kii si ya boro

AWON EGBE ONI MOTO (2)




    Eni to ba nwa ija awon omo egbe oni moto NURTW,ni ko pe won ni agbero, won o feran oruko yi rara. O tewon lorun kee pe won ni yunionu (union). Oun kan ti awon eniyan ko le gbagbe kiakia ni pa won ni ajaku akata ti won maa n ja nigba kan ri. ti won ba fee gba gareeji. Won lepa eniyan tabi ki won se ara won lese, won si loogun lowo. Sugbon otito ibe ni wi pe, aye atijo nigbogbo iyen ti sele, nigbati ijoba igba naa faye gba awon nkan bee. Sugbon nigba toya paa paa julo ni igba ijoba Fashola eni to ba dalu ru to ri wi pe o fe gba ijoba yoo pe ni kirikiri.
     Kosaye fun jagidi jagan laarin won mo, apa ijoba ti ka won lori iyen. Loni awon olori pipe ati awon ojogbon naa ti dara po mo won. Won si ti ngba awon to kawe si se.
      Teletele ri oju ko si lara ise yi, nitori awon eniyan ko mo wi pe owo wa ninu ise naa, sugbon nigba to ya inawo yafunyafun ati ise karini ti awon kan nse laarin won ti je ko han gbangba si opo eniyan pe awon wonyii ni owo lowo. Awon eniyan nri bi awon olori won se ma n ba owo je loju agbo awon elere fuji.
     Iriri mi laarin won ni wi pe ki i se gbogbo won ni won feran afefe yeye bayii. Awon kan wa ti ki ifa wahala ti won kii pariwo ti awon eniyan gan kosi da won mo, ti won sin se nkan ire.
     Amoran mi fun awon olori won ni wi pe, ki onikaluku ni nkan pataki ti won nse fun ilu. Bi apeere awon chairman kookan lee ni akanse eto isagbateru eto eko fun agbegbe won (Educational foundations).

AWON EGBE ONI MOTO 1




     Awon egbe yi ni won pe ni won pe ni omo egbe nasona. Awon ni won nsakoso awon awako moto ati awon agbowo oko. Meji ni won pin si. Awon kan ni roodu (Road) awon ekeji ni ti nasona. Awon ti mo n ko nipa re niti nasona (N U R T W).
     Olu ile ise won wa ni Abuja. Won si ni olu ile ise kaakiri ipinle kookan ni orile ede yi. Okan lara ise won ni lati soju awon onimoto, lati mojuto bi ise won se nlo. Lati mojuto garaaji oko, ati lati ri wi pe alaafia joba larin awon onimoto.
     Eto isakoso egbe yi wa ni ipele-ipele. Eyi ti o sunmo awon onimoto ju ni yuniti (unit). Ti unit kan ba wa won maa n fun un loruko bi apeere karowosaye, Aberu eniyan, Sopetie ati bee bee lo. Unit kookan si maa ni awon oloye tire. Nibe won a ni alaga (chairman), igbakeji alaga (vice chairman), (secretary), akapo (Treasurer) ati organizing secretary.
     Leyin unit, won maa n ni branch, branch ju unit lo. Branch miiran le ni unit marun, mewa, meta tabi ju bee lo tabi ko ma to bee. Awon naa maa nni awon oloye won bi won  se wa ni unit naa.
     Leyin state lo wa kan National. Agbara ati ase ti ipele kookan ni si ju ara won lo. Ilu eko ni ise nasona ti lapeere ju ni gbogbo ipinle, nitori wi pe oun koun ti eko ba se,ara ni won fida. Ilu eko ilu owo si ni.

Saturday 3 September 2016

OWE YORUBA




Owo aidile ni i yo koriko lo ju ana e
it is an idle hand that has time to remove speck of grass from his in-laws' eye

KATAB




         Awon eeyan wonyi ni a npe ni awon ara Atyap ti a won Hausa n pe ni “Kataf”. Won je awon eya ti o n gbe ni ibile Zangon – Kataf, ni ipinle Kaduna. Ede Tyap ni won nso. Awon eniyan wonyi ngbe ni awon apa ibiti asa Noki(Nok culture)  wa. Asa Noki ni awon ti won maa n mo awon ere Terra- Cotta. Awon iran Shokwa ni o wa ni kawo ojo(rain). Awon iran Agba’ ad ni won wa nidi ogun jija.

FULANI (2)




     Awon Fulani le ni milionu lona ogun ni ye. Won wa lara awon eya eniyan to tankale julo ni ile Afirika. Ede Fula yi lo so gbogbo awon Fulani po ati asa ti won npe ni pulaaku. Milionu metala ninu awon Fulani  je darandaran (normadic). Fulani ni eya to n sise darandaran to poju lo ni gbogbo agbaye. O fere je idameji gbogbo orile ede Guinea ni Fulani. Won po gan ni ori oke Fouta D jallon ni Guinea.

FULANI (1)




     Awon Fulani maa n so ede Fula (Fulfulde/ Pulaar/Pular). Ede yi tan ka orile ede to le ni Ogun (20) ni iwo orun Afirika ati aarin gbungbun Afirika. Iyato bintin  ni ede naa fi yato lati orile ede kan si ara awon.
     Ede wolof ati serer lawon ede meji to sunmo ede fula. Ede yii naa ni awon ara Toucouleur ni Senegal nso, bakannaa ni Guinea, Cameroon ati Sudan. Ede Fula ni orisirisi isori oro oruko to le ni merinlelogun (24) Kaakiri eya ede naa. Bo tile je wi pe won maa n so wi pe okan naa nigbogbo ede Fulani. Awon atunmo bibeli tun mo bibeli si isori ede Fulani Mesan koto kari gbogbo awon to nso won, kosi too ye won yeke. Ede Fulani wa lara ede a jumolo (official) ni orile ede Senegal ati Naijiria.

IDOMA




     Awon idoma je awon eya ti won ngbe apa iwo oorun ipinle Benue, ni orile ede Naijiria. Lara won naa wa ni ipinle Cross Rivers ati Nasarawa. Awon idoma je jagunjagun ati ogboju ode, si be won feran awon alejo ati alaafia. Won to milionu meran niye. Iduh ni baba nla awon Idoma. Iduh ni awon omo wonyi.
     Ananawoogero to je baba fun ara igwumale, Olinaogwu to je baba fun ara Ugboju, Idum ti o bi awon ara Adoka, Agabi ti o bi awon ara Otukpo, Ode ti o bi awon ara Yala. Opolopo awon omo idoma gba wi pe Apa ni awon baba nla won tedo si. Nitori ise pataki Apa ninu itan won, Ibile kan wa ni Benue ti won n pe ni Apa, awon kan lagbo oselu si nja wi pe ti won ba fun awon Idoma ni ipinle, O ye ki won pe e ni Ipinle Apa. Awon onimo ijinle nipa iwadi fi di re mule wi pe baba nla kan naa lo pa awon idoma ati igala po. Idoma ni eya ede keji to poju ni ipinle Benue, won si wa kaakiri ibile mesan. Gege bi asa, awon okunrin lo ma an gunyan fun awon iyawo won. Awon ila pupa ati dudu ni awo awon ara Idoma. Obe won to gbajumo ju ni obe Okoho. Won maa nfi ewe Okoho see.