Sunday 21 August 2016

BIROM




     Birom je eya kan lori le ede Naijiria lati ipinle Plateau. Awon ti o n so ede  yi to milionu kan leniyan. Won sunmo Hausa sugbon won kii se Hausa. Won tankale si ibile merin (Ariwa jos,guusu Jos, Barkin ladi ati Ri yom. A tun ri won ni guusu Kaduna.
     Ede Birom ni awon ara Birom maa nso. Won maa n se odun Nzem – Berom lodoodun ni osu keta tabi ikerin.
     Ise agbe ati ise eran dida ni o wopo laarin won. Won feran ise ode eran pipa debi wi pe eyi to poju ninu oruko ti won maa n fun awon omo won je oruko eranko. Bi apeere pam, Dung, chuwang.Oruko eniyan ni“Bot” o si tumo si "opolo". Oruko oye oba awon Birom ni Gbong Gwom Jos.

No comments:

Post a Comment