Monday 15 August 2016

ABANIJE (2)




     Eleyii sele nigba tii mo wa eko olodun karun. Ase idanwo taamu akoko tan. Bi a se wo le taamu keji ni mo gbo wi pe Oluko wa to n ko wa ni imo baoloji lawon fee ri mi ni kia kia. Won ko mo mi. Won fi oruko mi welo wi pe kiwon pe eni to nje bee wa.

     Nigba ti mo si de odo won, won fi iwe ti mo fi se idanwo baoloji mi han mi, wi pe tani onii, mo yee wo mo si so wi pe temi ni, sugbon leyin iwe yii, pepa miran tun wa leyin re ti won fi igbale so o po mo eyi ti mo fi se idanwo mi. Ninu pepa ti o wa leyin te mi yi, won fi gege pupa ko awon idahun ise naa sinu re, lati le je ko ri bi wi pe mo gbeegun ninu idanwo naa.
     Nigbati won bi mi wi pe bawo lo fi jebe, mo so wi pe nko mo nkokan ni pa re. Awijare mi si ni wi pe, ko seese ko je wi pe mo jiwe wo tan ki n tun wa le iwe ti mo fi jiwe wo mo iwe ti mo fi sise. Oluko to samojuto idanwo ko de fe sun kan mi wi pe won ka iwe momi lowo.
     Oluko kan wa ni ibi ti a tin so oro naa, won fi lo won, won si so wi pe amoran awon ni wi pe ki won fun mi ni iwe idanwo miran ki ntun gbogbo idanwo naa se lai mura sile to ba je wi pe looto nko mowo mese. Gbogbo wa gba bee. Won fun mi ni we, ati ibeere mo si joko lati tun idanwo naa se. Bo tile je wi pe osu meji abo seyin ni a ti se idanwo naa tele. Opolo mi sipe sibe. Paapaaa paa mo ti se tan, oluko naa maaki re, mo si gba ida aadorun ninu ogorun lori idanwo ti mi o mura re sile.
     O wa ku si owo oluko lati mu eyi to wu, nigba ti o han gbangba wi pe mo mo ise naa dunjudunju. Won lo esi akoko fun mi. titi dola akomo eni to se ise buruku yi.

No comments:

Post a Comment