Saturday 9 July 2016

Oriki Awon Ijebu



ORIKI AWON IJEBU
E e e e e e e e e e
Awa niyin eeyan, awon ode omo digbolugi
Awon niwon maa nso pe ijebu oloriki
Iro patapata niwon npa, eyin ijebu momo oriki baba teyin
Wonni  boba wun jebu awun ni e ni winiwini
Bo ba wun jebu awun ni e ni winiwini
E e mope boba wun jebu afenire yooku sodun agemo.
Eyin omo alagemo afiyi jo wini
Won okuku mekun wo gbosara ri
 Iba lomekun wo gboremo
Eyin lomo afinju jebu tii foko ree japena.
Omadunrun made o, nle madunrun mosuu medieyege
Omaa ladie, ogogo moja
Eleyi tii le yeye bi a wo tiigbin tiigbin.
Omadie borogun, bogoolele
Ara orokun, ara ora die
Omo hun – un seni oyoyo nyo.
Oyoyo mayomo,un tin seni o lee pani
Omo dudule,omo be e se njosi
Pupa tomo bee se okuku sinle
Omo moreye maa maa roko
Moroko tan eye siitilo
Omo moni su  nle mi o lo be
Obe tii be leye, omo le baba tobi won lomo
Loni mori gba lodo baba tawon
Ome nile made, o mo onile mawo mawo
Omo onile kan ajoji won o gbodo wo
Ajoji toba wo  gboooro, yoo de ni e bora nile
Baba tobi won lomo
Ijebu omo eere niwa.
Omo olowo sembaye, kowo kukusi to gbode
Koto dowo eru, koto dowo omo
Iran ijebu nina wo dollar ko oyinbo togbowode
Oyinbo gbowode lowo oun posi
Omo elekunje ajowiire
O osa jendabi onileyi
Ni won se nwipe
Igbe jebu owo,ito jebu owo
Kekere jebu owo, agba jebu owo
Dudu jebu owo, pupa jebu owo
Kukuru jebu owo, giga jebu owo
Gbogbo jebu timo mo niwon lowo lowo o
Ijebu nle omo abere ni wa.
(Baba Ajobiewe lo fi kewi, kin to koo sile)

No comments:

Post a Comment