Tuesday 26 July 2016

ORI YEYE NI MOGUN TAI SE LOPO




      Nii igba lae lae Mogun je ibi ti won maa nfi awon odaran ponbele si laye atijo. Ni be ni won maa nbe ori awon odaran si. Enikeni ti won ba mu esun re wa ba Oba laaye atijo, ti eleeri sigbe e wi pe o huwa odaran, ipaniyan, idigunjale, ifipa banilopo,iru won ni won nberi wo si Mogun.
       Ni opolopo igba ni o si je wipe opolopo awon ti won ngba idajo lati lo si Mogun ni o je wi pe won kii se alaise, to kan je wi pe won dunrun oran mo won ni tabi wi pe won puro mo won tabi ki won si won mu. Bi apeere bi awon odomokunrin meji ba n du obinrin  kan naa ti okan ninu won wa nwa ona ika ti o nyoo fi koba orogun oun. O wa lo dogbon ledi apo po pelu awon ti won lo gbe oku eniyan sinu oko eninaa. Oba wa dajo wi pe ki won lo be ori eninaa si Mogun nitori wi pe won fi esun apaniyan kan.
      Eleyii ni awon agba  ri ti won fi so wi pe, ori yeye ni Mogun tai se lopo.
     Oun iyalenu ni wi pe oun to n sele lati jo yi si wa titi do ni. O tile wa buru jayi loni.
     Opolopo awon ti won wa ni ogba ewon wa loni ati awon ahamo awon olopaa kaa kiri ni won ko mowo mese lori oran ti won fi sun won.
     Bi apeere, mo wo eto kan lori ero amohun-maworan ni ojo kan ti won nfi oro wa awon abode elewon ti ijoba tu sile ni ojo ominira. Okan ninu won ti o je omo ahusa ni awon  olopaa ko mo roga ni igba ti o wa ni omo ogun odun, o si wa ni atimole fun ogbon odun ki ijoba Obasanjo to o wa tun sile. Lati igba ti won tifisi atimole, odindi ogbon odun ni o fi reti wi pe ki won gbe ejo oun losi ile ejo sugbon ti won ko gbe ejo re wole ejo. Won o da jo fun un ba kan naa kori itusile.
     Opolopo awon eniyan ti o wa ni atimole loni lowa legbe yii. Won mu won fun esun ti won ko mowo ti won ko mese, sibe won  kogbe won losi ile ejo ki won le so tenu won bee won o ro mi ni ra.
     Mo gbo ti ogbeni kan ti o lo odun mewaa lati mole lori wi pe, laaro ojo kan, ni idaji o lo waasu ihinrere lai mo wi pe awon ole ja ladugbo naa moju, nigba tii awon olopaa nle ole naa o sa gba apa ibi ti ogbeni naa tinwasu nitosi moto kan nibe, ole yii sagba iwaju oniwasu naa, osa seyin oko, osi gba be salo, sugbon nigba ti awon olopaa de ogbeni to n waasu ni won ri ti won si muu lo wi pe oun lo jale.
    Melomelo ta won ti ole fi moto won jale, ti o wa je oni nkan ni won mu, tabi ti awon ti won dede ba oku eniyan lenu soobu won tabi ninu agbala won.
     Ilukilu ti ori aise bati po latimole bayii ko dara rara. Iru ilu bee kii lalafia, ilu be ki fara rogbo. Eku kii ke bi eku, eye kii ke bi eye. Ilu ti eje alaise ba tipo bayii kii riyonu olorun nitori esan eje yoo maa ke lori won.

3 comments: