Monday 4 July 2016

FAARI ASEJU




     Faari je oun ti a le pe ni ako sise, to je asa to wopo laarin awon odo ati agunbaniro. Otun yato si oge sise, bakan naa won si wonnu ara won. O je asa olaju ti awon odo maa n fe ko. Faari je asa ti o ma n farahan ninu ihuwasi, oro siso, ara mimu, irinrinrin, lilo eya ara kan lona to tun yato. Opolopo igba nifaari maa nje asa ti a ko wole nipa wiwo awokose awon ti a ro wipe won laju juwa lo

    Faari je ona kan ti odo langba fin fe ki awon eniyan mo wipe oun wa nile. Won fe fi han wipe asiko awon yutu re. Bi a ba so wipe eniyan gbo faari iyen ni wipe eni naa mo pepe furu se, eni naa feran ati maa lo nkan igbalode, osi feran ati ma ko asa igbalode, tabi dasa igbalode. Yoruba bo won ni igba ara lan bura enikan ki ibu sango leerun. Ko see see lati so pe ki ewe ti ojuure bati la si faari sise ma see, sugbon oun ti o se Pataki lati mo ni wipe iwon-tun – won-si ni leke ogbon eni bi ologbe Sikiru Ayinde se ko morin re.
     Ti eniyan  yoo ba se faari ko ma se faari gbemi-gbemi tabi eleyii to nso ni daabo ara lojo iwaju,ko gbodo je eleyii ti atunbotan re koni dara lojo iwaju. Faari aseju a maa ko bani bi apeere awujo wa je awujo to gbe asa omoluabi laruge. lara abuda omoluabi si ni iwon tun wonsi wa. Bi faari omo birin ba poju, oju alasewo ni awon eniyan mama fi woo lopo igba. Bi i keniyan to oju, imu,ereke, ko luti bi ona merin, ko wooso ko maa fi ihoho re han je awon asa ti Yoruba ki i fi oju eniyan tonilaari wo won a si ri iru eniyan be bi eniti ko ti ile ire jade.
     Atunbotan buburu miiran to tun wa ninu faari aseju ni wi pe ni opolopo igba kii so eso rere fun ilera eni to nse iru re leyin wa ola. Bi apeere eni to lo bora ni tori faari si se, nigbato baya ti ara ba n da ra agba, awon isoro ilera kookan ama jeyo. Bi won ba fee se ise abe fun won yoo di  isooro tori ara won le soro lati ran. Iru won ni o maa nsagbako arun jejere ti ara. Orisirisi awon kemika ti won lo ni gba ewe maa n lo sa pa mo si ara lati je jade lojo ale.
      Atunbotan bururu miran ti faari aseju maa n mu wa ni wipe, bi asa ba ti di baraku fun ara, kii se gbaboro. Bi apeere odomokunrin to n rin to ndegbe rin lai jepe ese ndun won, ti won nfi sako rin, ti won ntiro ese rin lati fi se faari, nigba to baya iru irin bee ko ni ye ojo ori won mo, ti won ba fee wa se atunse koni wa rorun mo lati se. Ara won atidi eja gbigbe ti ko see ka mo.
      Idimiran ti faari aseju ko fi dara ni wipe ofin awon iwe mimo mejeeji kofaye gba aseju.iwontun iwonsi ni awon lemonu mosalasi nki gbe beeni iwe peteru so wipe ki obinrin je kii ewa oun je ti iwa tutu ati okan to dake je. Oti le so wipe ki a ma se jekii ewa wa duro lori awon oun eso ati aso olowo iyebiye ti ale fo juri.
       Faari aseju le je ki won mu odomokunrin  fun ole ni gba tii olopaa koba le so iyato laarin imura re ati ti awon igara olosa ti won nwa. Omobinrin ti dokita oju ko fun ni igo oju to nkan go moju kaakiri bope boya oju amaa wo baibai.
       Faari aseju kii bi mo gidi eje ka se oun gbogbo leso leso.

No comments:

Post a Comment