Tuesday 5 July 2016

ORE TI MO FERAN JU



                 
   Oruko ore ti mo feran julo ni Tope Adesiyun. O je omo bibi ilu Akure. Omo idile oba ni ise. O je eniyan giga. Orewa lokunrin. O mo oro so. Olorun si jogun ogbon fun. O loyaya, ara re si yomoyan. Pabanbari re ni wi pe o je eniyan ti o ni feran olorun ti o si beru olorun tinutinu re. Olooto eniyan ni. O feran nkan ti emi.

       A pade ara wa ni odun egbaawa ole meje ni osu kokanla, ni ilu Kaduna, ni ibile Sanga. Ilu kan naa ni won pin wa si fun ise agunbaniro. Ise tisa si ni won fun awa mejeeji lati se, ile iwe girama ti o wa ni abule Gbonkoki ni won gbe emi lo, ti  won si gbe oun lo si ile eko girama to wa ni Fadan Karisi, sugbon gbogbo wa maa n pade ni eekan losu ni Guwontu fun ipade olosoosu awon kopa.
       Ninu egbe awon Kopa onigbagbo ni a ti pade. O wulo fun ise egbe naa, bi emi naa se wulo fun egbe naa. Nijo kan, leyin ipade awon kopa ni o so wipe oun yoo ba mi dele mi loni lati wa mo ile mi. Nigba tii ajo dele, a foro jomitoro oro lorisirisi. Ajiroro bojo iwaju waa se maa dara. Nibiyii ni ore wa ti bere.
        Nigbatii a lo se danwo NIM ni ilu joosi, ti a ko moo eniyan si, Tope ni o setoo fun ibi ti agbe. Bi o sesee, nko mo, sugbon awon eniyan naa se tojuu wa daradara. Ti a ba fidida temi nikan ni, boya oju titi ni nba sun, tori nko lagbaja nkan bee rara.
        Oun kan pataki ti o mu mi gbaa gege bi ore ti mo feran julo ni wi pe o huwa kan si mi, ni eyi to ku die kia se tan, eleyii ti emi ko ro pe o ye ko ri be, o dun mi, mo si pinu lati yera fun sugbon bi mo ti yera fun un to, ko fi mi sile, o wa mi kan, nigba tii a fi Kaduna sile. O gbera lati Akure o wa mi wa si Eko. Eleyii jo mi loju pupo. Wi pe ko wo ti iwa aibikita ti emi naa wu si, ko je ki okun ore aarin wa ja.
       Mo wa rii wi pe o je eniyan ti o ni okan agba, o simi iwa idariji ati ti irele. Lati igba naa ako je ki enikeni ko raarin wa mo. Opolopo ona ni a ti gba wulo fun ara. Ni opolopo igba ti mo ba fee se ipinu lori nkan, ti nkan naa si ru mi loju, bi mo ba ti pee taa foro jomitoro oro lori nkan naa, olorun yoo lo lati tan imole si ona mi lori nkan naa.
      Ni ojo igbeyawo mi oun ni o se ore oko fun mi. Ni ojo igbeyawo ti re naa, emi ni mo se ore oko fun oun naa. Ise Oluso Agutan loo nse, nigbatii mo si yan ise olukoni laayo.

10 comments: