Awon
ara Nupe ni awon Yoruba maa n pe ni Tapa. Eya yi fi di kale si aarin meji
Naijiria, ati ni apa oke Ariwa Naijiria, paapaa julo ni ipinle Niger, ni biti
won ti je eya to poju. Won wa ni Kwara ati Kogi bakannaa. Tsoede ni baba nla
awon Nupe, itan so pe o sa kuro ni Idah lati lo tedo si Niger ni eedegbeta odun
se yin. Ajo sepo to dan moran lo wa laarin awon Nupe ati awon Igbomina ile
Yoruba ati Oyo. Won nfe ara
won, won jo nse owo po, asa naa si pa won po. Itan
je ko ye wa wi pe omo Tapa (Nupe) ni iya to bi Sango, to ti fi gba kan je
Alaafin Oyo. Opolopo awon Nupe ni oyi pada si isilamu lati owo mallam Dendo, ti
o je oniwaasu nibii igba odun seyin, won si dara pomo ijoba awon Fulani ti
Usman dan Fodio da sile ni 1806.
Bi won ti darapo mo ijoba Fulani to, won
ko ko awon asa won sile, won ko lati pe oba won ni Emir. Etsu Nupe ni won npe
oba won. Ilu Bida bo sowo isakoso awon oyinbo amunisin ni odun 1897. Eni to je
Etsu Nupe (Bida) kii se omo Nupe, sugbon iran Fulani ni won ti wa. Opolopo awon
Nupe ni o ma a nko ila bi i ti omo Yoruba.
No comments:
Post a Comment