Saturday, 3 September 2016

FULANI (1)




     Awon Fulani maa n so ede Fula (Fulfulde/ Pulaar/Pular). Ede yi tan ka orile ede to le ni Ogun (20) ni iwo orun Afirika ati aarin gbungbun Afirika. Iyato bintin  ni ede naa fi yato lati orile ede kan si ara awon.
     Ede wolof ati serer lawon ede meji to sunmo ede fula. Ede yii naa ni awon ara Toucouleur ni Senegal nso, bakannaa ni Guinea, Cameroon ati Sudan. Ede Fula ni orisirisi isori oro oruko to le ni merinlelogun (24) Kaakiri eya ede naa. Bo tile je wi pe won maa n so wi pe okan naa nigbogbo ede Fulani. Awon atunmo bibeli tun mo bibeli si isori ede Fulani Mesan koto kari gbogbo awon to nso won, kosi too ye won yeke. Ede Fulani wa lara ede a jumolo (official) ni orile ede Senegal ati Naijiria.

No comments:

Post a Comment