Eni to ba nwa ija awon omo egbe oni moto
NURTW,ni ko pe won ni agbero, won o feran oruko yi rara. O tewon lorun kee pe
won ni yunionu (union). Oun kan ti awon eniyan ko le gbagbe kiakia ni pa won ni
ajaku akata ti won maa n ja nigba kan ri. ti won ba fee gba gareeji. Won lepa
eniyan tabi ki won se ara won lese, won si loogun lowo. Sugbon otito ibe ni wi
pe, aye atijo nigbogbo iyen ti sele, nigbati ijoba igba naa faye gba awon nkan
bee. Sugbon nigba toya paa paa julo ni igba ijoba Fashola eni to ba dalu ru to
ri wi pe o fe gba ijoba yoo pe ni kirikiri.
Kosaye fun
jagidi jagan laarin won mo, apa ijoba ti ka won lori iyen. Loni awon olori pipe
ati awon ojogbon naa ti dara po mo won. Won si ti ngba awon to kawe si se.
Teletele ri
oju ko si lara ise yi, nitori awon eniyan ko mo wi pe owo wa ninu ise naa,
sugbon nigba to ya inawo yafunyafun ati ise karini ti awon kan nse laarin won
ti je ko han gbangba si opo eniyan pe awon wonyii ni owo lowo. Awon eniyan nri
bi awon olori won se ma n ba owo je loju agbo awon elere fuji.
Iriri mi
laarin won ni wi pe ki i se gbogbo won ni won feran afefe yeye bayii. Awon kan
wa ti ki ifa wahala ti won kii pariwo ti awon eniyan gan kosi da won mo, ti won
sin se nkan ire.
Amoran mi fun
awon olori won ni wi pe, ki onikaluku ni nkan pataki ti won nse fun ilu. Bi
apeere awon chairman kookan lee ni akanse eto isagbateru eto eko fun agbegbe
won (Educational foundations).
No comments:
Post a Comment