Awon idoma je awon eya ti
won ngbe apa iwo oorun ipinle Benue, ni orile ede Naijiria. Lara won naa wa ni
ipinle Cross Rivers ati Nasarawa. Awon idoma je jagunjagun ati ogboju ode, si
be won feran awon alejo ati alaafia. Won to milionu meran niye. Iduh ni baba
nla awon Idoma. Iduh ni awon omo wonyi.
Ananawoogero
to je baba fun ara igwumale, Olinaogwu to je baba fun ara Ugboju, Idum ti o bi
awon ara Adoka, Agabi ti o bi awon ara Otukpo, Ode ti o bi awon ara Yala.
Opolopo awon omo idoma gba wi pe Apa ni awon baba nla won tedo si. Nitori ise pataki
Apa ninu itan won, Ibile kan wa ni Benue ti won n pe ni Apa, awon kan lagbo
oselu si nja wi pe ti won ba fun awon Idoma ni ipinle, O ye ki won pe e ni
Ipinle Apa. Awon onimo ijinle nipa iwadi fi di re mule wi pe baba nla kan naa
lo pa awon idoma ati igala po. Idoma ni eya ede keji to poju ni ipinle Benue,
won si wa kaakiri ibile mesan. Gege bi asa, awon okunrin lo ma an gunyan fun
awon iyawo won. Awon ila pupa ati dudu ni awo awon ara Idoma. Obe won to
gbajumo ju ni obe Okoho. Won maa nfi ewe Okoho see.
No comments:
Post a Comment