Awon ara Efik je eya ti won tedo si apa guusu
ila oorun orile ede Naijiria, ni ipinle Cross River. Ede Efik ni awon ara Efik
maa nso. Lati Arochukwu ni won ti wa tedo si ipinle Cross River. Lati Nubia wo nu
Ghana ni won ti tedo si Arochukwu. Won si ba won gbe gege bi alejo fun bii
erinwo odun, ki ija too tu won ka. Awon ara Efik kan ngbe ni guusu- iwo
oorun
Cameroon ninu Bakassi. Itan so wi pe awon ara Uruan ni won fun won ni Oruko
“Efik” ti o tunmo si wi pe “ki eniyan fe je gaba” nitori eniyan lile niwon. Itan
kan so wi pe awon Efik ti ngbe ni Calabar o le ni igba odun seyin. Won yan ise
eja pipa laayo won si tun se owo karakata. Won ni egbe ogboni ti won npe ni
Ekpe. Lara awon gbajugbaja omo ilu Efik ni Shirley Bassey, Hogan Bassey, Iyanya ati Margaret Ekpo.
No comments:
Post a Comment