Saturday, 3 September 2016

KATAB




         Awon eeyan wonyi ni a npe ni awon ara Atyap ti a won Hausa n pe ni “Kataf”. Won je awon eya ti o n gbe ni ibile Zangon – Kataf, ni ipinle Kaduna. Ede Tyap ni won nso. Awon eniyan wonyi ngbe ni awon apa ibiti asa Noki(Nok culture)  wa. Asa Noki ni awon ti won maa n mo awon ere Terra- Cotta. Awon iran Shokwa ni o wa ni kawo ojo(rain). Awon iran Agba’ ad ni won wa nidi ogun jija.

       Awon iran Aku ni won nmoj to esin Abwoi. Awon Katap ati awon Hausa ti ngbe ni Zangon Kataf lati odun 1750. Ni odun 1992, osu keji, ija sele laarin awon Atyap ati awon Hausa lori oro oja, emi to ku nitori re leni ogota. Nigba ti o di osu karun odun kanna, ija miran tun sele laarin awon mejeeji ti iye emi to lo si le ni erinwo (400). Nigbatii iroyin ija yi de Kaduna, awon odo langba Hausa bere si ni pa awon kirisiteni laiwo te ya won.leyin ija yi, ijoba Jenera Babangida fesun kan awon metadinlogun, won si dajo iku fun won. ko si omo Hausa kookan ninu awon metadinlogun ti won fe sun kan yi.
     Ni 1996, won fun awon Atyap ni ijoba ti won, won yan baale tiwon.Ni odun 2007 ijoba gbe ade fun bale won. Won soo di oba kikun.ni isori awon oba akoko(first class).

No comments:

Post a Comment