Saturday 3 September 2016

FULANI (2)




     Awon Fulani le ni milionu lona ogun ni ye. Won wa lara awon eya eniyan to tankale julo ni ile Afirika. Ede Fula yi lo so gbogbo awon Fulani po ati asa ti won npe ni pulaaku. Milionu metala ninu awon Fulani  je darandaran (normadic). Fulani ni eya to n sise darandaran to poju lo ni gbogbo agbaye. O fere je idameji gbogbo orile ede Guinea ni Fulani. Won po gan ni ori oke Fouta D jallon ni Guinea.

     Orisi Fulani meta lo wa. Akoko ni awon Fulani Darandaran ti kii gbe ibi Kankan,won maa nrin lati ilu si lu ni.Awon keji ni awon Fulani ti won maa n gbe ibikan fun igba die bi odun meji si marun lati sise.Awon keta ni awon Fulani ti won fi di mule ni awon ilu kaakiri. Awon kii si kiri. Awon niwon wa ni Birnin Kebbi, Gombe, Yola, Jalingo,ati bee bee lo. Ni awon ilu bi Mali ati Senegal, ti eniyan ba gbo Fulani sugbon ti ko wa lati eya Fulani, iruwon ni won npe ni Yimbe Pulaaku.
     Eni to ba je eya Fulani gangan ni won je Fulbe pelu Pullo ati Dimo. Awon iran kan tunwa ti won je onise owo bi alagbede, gbenagbena, telo ati bee bee lo. Awon iran kan wa to je wi pe eru ni baba nla won; awon ni Maccudo, Rimmagbe, Dimaajo ati baleebe. Sugbon loni gbogbo eya yi ni won lo minira labe ofin

No comments:

Post a Comment