Friday 16 September 2016

AWON EGBE ONI MOTO 1




     Awon egbe yi ni won pe ni won pe ni omo egbe nasona. Awon ni won nsakoso awon awako moto ati awon agbowo oko. Meji ni won pin si. Awon kan ni roodu (Road) awon ekeji ni ti nasona. Awon ti mo n ko nipa re niti nasona (N U R T W).
     Olu ile ise won wa ni Abuja. Won si ni olu ile ise kaakiri ipinle kookan ni orile ede yi. Okan lara ise won ni lati soju awon onimoto, lati mojuto bi ise won se nlo. Lati mojuto garaaji oko, ati lati ri wi pe alaafia joba larin awon onimoto.
     Eto isakoso egbe yi wa ni ipele-ipele. Eyi ti o sunmo awon onimoto ju ni yuniti (unit). Ti unit kan ba wa won maa n fun un loruko bi apeere karowosaye, Aberu eniyan, Sopetie ati bee bee lo. Unit kookan si maa ni awon oloye tire. Nibe won a ni alaga (chairman), igbakeji alaga (vice chairman), (secretary), akapo (Treasurer) ati organizing secretary.
     Leyin unit, won maa n ni branch, branch ju unit lo. Branch miiran le ni unit marun, mewa, meta tabi ju bee lo tabi ko ma to bee. Awon naa maa nni awon oloye won bi won  se wa ni unit naa.
     Leyin state lo wa kan National. Agbara ati ase ti ipele kookan ni si ju ara won lo. Ilu eko ni ise nasona ti lapeere ju ni gbogbo ipinle, nitori wi pe oun koun ti eko ba se,ara ni won fida. Ilu eko ilu owo si ni.

No comments:

Post a Comment