Monday 3 October 2016

ITSEKIRI




    Awon ara itsekiri je awon eya to wa lati apa Niger Delta lori le ede Naijiria, ni ipinle Delta. Awon omo itsekiri leni million kan niye. Won wa ni guusu Warri, Ariwa Warri ati guusu – iwo- orun Warri. Awon omo Itsekiri naa wa ni Edo, Ondo, Sapele, Benin, Port Harcourt ati Abuja. Awon omo Itsekiri maa n pe ilu won ni “Iwerre”, won mu oruko yi lati ara ewe “ewerre”, ni ede bini ti o tumo si inu rere ati alaafia. Agbegbe yi je okan pataki lara
ilu ti o ni epo robi ati afefe gaasi, osi tun ni ibi ifopo robi.ilu Warri si je ilu nla ti o ni orisirisi eya, o si je olu ilu fun oro aje ati ile ise nlanla ni gbogbo Niger Delta. Ede itsekiri je ede to sunmo ede Yoruba ati Igala. Awon ara itsekiri ni awon eni akoko ti o koko ni ajosepo pelu awon Oyinbo Potogi (Portuguese) lori le ede Naijiria.
     Awon elesin kirisiteni lo poju ninu won. Opolopo awon ti won je omo itsekiri je awon ti awon obi won ni adalu orisirisi eje ninu. Olu ilu itsekiri ni Ode- itsekiri. Awon omo itsekiri maa n kawe, won si lowo lowo. Won wa lara awon ti won koko ka we gboye ni orile ede yi. Bi apeere: Olu ti Warri. Awon omokunrin itsekiri maa n wo saati alapa gigun ti won n pe ni kemeje, won si maa nro iro jooji (George wrapper), won a si de fila to ma n ni iye ninu. Awon obirin won lo maa n wo bulaosi ti won si maa nro iro jooji (George) won si maa n we gele didan ti o maa ni owo eyo lara. Ise apeja ni se won.
     Awon Eeyan Pataki to je omo ilu itsekiri
Ø  Emmanuel Uduaghan (Gomina ana ni Delta)
Ø  Festus Okotie- Eboh (Oloselu).
Ø  Lizzy Gold Onuwaje (Elere Oritage)
Ø  Amatosero Ani (Elere oritage)
Ø  Amaju Pinnick (Alaga NFF)
Ø  Grace Alele- Williams
Ø  Ladi Utieyione
Ø  Ayo Oritsejafor (Oluso aguntan)
Ø  Oritse Femi (Olorin)
Ø  Omawunmi (Olorin)

No comments:

Post a Comment