Thursday 30 June 2016

Ko leta si ore re ni ilu odikeji lati so ni ekunrere ohun ti oju re ri nipa rogbodiyan to be si le nigba ti awon adingujale wa si adugbo re( WAEC QUESTION)



                                                                                                                                5, Ladugbo
                                                                                                                               Agege, Eko 
                                                                                                                               12-03-2016
                                                                                                                              



   Ore mi owon,
              Idi pataki ti mo fi ko leta yii si o ni lati salaye oun ti oju mi ri lori rogbodiyan to sele ni gba ti awon adigunjale wa si adugbo mi ni oru ojo keta, osu kerin odun yii. Mo ro wi pe alaafia ni o wa pelu gbogbo ebi re, gegebi emi naa se wa nibiyi.

              Goke oree mi, oye koo ba awon ti ori ko yo ninu rogbodiyan naa gbegba ope ni o. Ni dede agogo mokanla ale ni awon atilaawi won yi wo adugbo, won gbe oko molue meji wa. Iye awon ti won si je mejidinlogbon. Won ko orisirisi awon irinse ati awon oun elo ologun, bi ibon atamatase, ibon dobubareli, ibon eekefotisefun po rere, se oko gbagbe wipe ile oloke ni ile wa, omu ki ororun lati ri gbogbo nkan ti o sele ni kedere.
                Ni kete ti won de ni agbenuso won ti gbe ero megafoonu senu, o ki awon ara adugbo,  o se wa pele, o pe oruko ara re ni makalaki omo eleja, o so wi pe idikansoso ti awon fi de bawa lalejo nilati wa gba isakole awon ninu awon ibukun tolorun fun wa ladugbo wa, o si ro wa pe ka fowo so wopo pelu awon, lati mu ki ise naa ju se fun awon lati se. O si so fun wa wi pe awon mejidinlogbon ni iye awon ta won wa. Awon si wa de ba wa lalejo pelu gbogbo oun ijagun igbalode ati ti ibile. Oni awon yoo ma kan lekun lati oju le si ojule ki a ma se agidi rara.
          O wa pase fun okan ninu won ti ope oruko re ni Diboi wipe ki o fi irin tutu owo re powe di e fun wa, ki a le mo wi pe kii se seresere, leekannaa ni abere si ni gbo kau, kau, kau, kau,kau, kau bi ona ogun igba, iro awon ibon naa rin le domu domu bii gbati ogun abele de, mi o ni paro tan e, nse ni mo to sara lai mo, nitori eru, o wa pase fun diboi ki o sin mi naa, o so fun wa wipe eleyii ti okerejulo ninu awon irinse ti awon ko wa ni a gboseewo yen. Oni boba wun wa ka pe awon soja ni jaji tabi awon olopaa ko gberegbe wi pe ko si baba nla enikeni to le koju awon.
          Awon ile olowo po ni adugbo wa, awon ni afojusun won. Won gbo itanilolobo wipe awon kan gbe owo kongilato ti ijoba fun won wa le. Won pin ara won si gbogbo ojule to wa ladugbo, won jalekun wole, enikeni ti ko ba tete silekun won alu nilukulu, won yinbo fun awon miran lese. Won ba awon iyawo ile ati olomoge sun. Bi obinrin ba ba won sagidi won a pe arawon jo bii merin, marun lati baa sun.
        Nigbatii olode waa maa fi de ni agogo mejila ku ogun iseju, won ti fo le jina, won tin ko awon eru ati owo sinu molue, ori loko olode wa yo wi pe orin tifura tifura. Oun naa lo pe awon olode egbere to ku ati awon opisi kaakiri. Awon naa ba sigunde. Pelu oko danfo meji.
     Nse ni adugbo wa di oju ogun lojo ti a wi yi. Botile je wipe ibon tawon olode ko gbowo to ti awon ole yii, won ni awon ogun buruku, abenugo lowo. Awon kan ninu awon ole nfole lo, beni awon kan ninu awon ole toku doju ko awon olode ati opisi won yi. Won wa nro ota ibon lu ara won ni kosekose. Ota ibon ko ran awon olodo beni awon ole nyera fun eyiti awon olode nyin.
     Bi wahala yi ti po to, ni oju le kewaa, malamu Hausa kon wa ti osun ni wa ju ita ile re, ko tile bikita lati sa wole, eru kobaa rara, ota ibon ko si baa.  Okan ninu awon ole yii ri ti on sun ni agbalaa re, agbala naa ni geeti. Ole yii ti oruko re nje Diboi, binu sii, o mu igo, o si so igo si malamu naa, sugbon igo naa haa si enu irin geeti naa, ko ba malamu yii, inu wa bi malamu naa wi pe oun o da si won lataaro o, ki lode ti o waa nwaja oun. Omu epe senu osi pase fun Diboi ko rin lo. Diboi is rinlo patapata. O rin lo fin in fin in.
     Ninu rogbodiyan yi, ibon ti ba odo marun ati alaboyun meji nibi ti won ti nsa kijo ki jo. Apa awon opiisi ko ka awon olosa yi, nigba too ma fi di owo agogo meji aabo oru, agbo oun fere moto awon olopaa, laipe won darapo mo awon opiisi lati dojuko awon olosa naa.  Ogun naa le ore, nigbato maa fi di agogo merin oku awon ole tidi mewaa nile, tawon opiisii ti di mejo, nigbati tawon olopaa je meta.
      Nigbati awon adingunjale rii wipe ota ntan lo lowo won, won bere si ni sa lo leyo kookan. Won o le gbe awon moto molue won lo mo, sugbon won ko gbe awon owo ti won ti ko sile, won nsalo leyoleyo, nigbatii awon die ninu won si dojuko awon olopaa,  kan maba  bere sini le won. Awon to ku  bere sini pariwo oruko Diboi, Diboi, Diboi, eleyii ti malamu Hausa yen sepe fun ko rin lo, eleyii lotun mu kan pe, nitori won o ri oku ati aaye Diboi. Awon olopaa tun pa meji si laarin awon toku, nigbatii awon meji to ku feyin rin salo. Awon olopaa le won lo, nigbayen ni awon aradugbo tu jade, pelu igbe lala, fun awon to loku nile, awon ti won ko gbe eruwon bere si nii ko eru won, awon ti won ko owo won lo si bere sini gbera sanle.
       Nigbato ya iroyin so fun wa wipe owo awon olopaa te gbogbo awon ole to ku naa, ile ejo sii dajo ewon gbere fun won. Ore, aboori wipe rogbodiyan nla ni. Mo fe ko ba mi dupe lowo olorun.
Temi ni tire
Temitope

13 comments: