Abeokuta ni ilu ti o tobi julo
ni ipinle Ogun. Ilu yi fidikale si apa ila oorun odo Ogun. Lara awon oun ti a
le ri ra loja won ni epo pupa, igi gedu, roba, isu, iresi, agbado, owu, ori ati
bee be lo. Idi ti won fi n pe e ni Abeokuta ni wi pe abe ori oke Olumo ni ilu
naa wa.
Oju ona reluwe wa, ti o lo lati
Eko si Abeokuta, o si je kilomita merindinlogorin(77). Won se oju ona reluwe yi
ni 1899. Awon ona miiran ti o tun wo Abeokuta ni Ibadan, Ilaro, Sagamu, Iseyin
ati Ketou.
Sodeke ni o te ilu Abeokuta do ni 1825. Gege bi ibi aabo lowo awon olowo
eru lati Dahomey ati Ibadan. Awon ara Egba ni won koko tedo si Abeokuta.
Abeokuta di Olu ilu ipinle Ogun ni odun
1976. Abeokuta je ilu ti a mo odi yi ka, lara re si wa titi do ni. Ake ni
Alake, oba won ngbe. Ile iwe giga ti yunifasiti ise agbe wa ni Abeokuta. A da
sile ni 1988. Die lara awon gbajugbaja omo Abeokuta ni
Efunroye Tinubu
MKO Abiola
Olusegun Obasanjo
Jimi Solanke
Funmilayo Ransome –Kuti
Bola Ajibola
Oloye Akintola Williams
Wole Soyinka
Ebenezer obey
Dimeji Bankole
Sir Shina Peter
Olusegun Osoba
Nice
ReplyDeletegood
ReplyDeletebut sir how can i found the name of recent and past kings in abeokuta