Tuesday, 28 June 2016

ITAKUROSO TI O WAYE LAARIN AKANNI ATI ABEO LORI IWULO AWON OLOPAA LAWUJO WA.





ABEO: Oro awon olopa ilu yi gan ti su eniyan. Ni kope kope yii ni okan ninu won to muti yo, lo yinbon fun obinrin oloyun to nlo jeje re. se ko tile si ounkoun taa ri yanju lori le ede wani?
AKANNI: ko kuku ri bee rara. Okan lara awon kanda inu iresi ni ogbeni naa je. Ako le so wipe tori wipe enikan ko dara ka wa so wipe bee ni awon toku naa ri
ABEO: se iwo ri apeere nkan rere kan ti awon olopaa gbe se lori le ede yii.
AKANNI: se bi eeyan ni obirin koburu olopaa ti a gbo nipa re ni Agege nijo si. Ti  okunrin ole kan naa ibon si sugbon ti obirin  olopaa yi to wo iro ati buba, gba ibon lowo okunrin ole to na ibon sii. Okunrin melo lole se iru re. Gomina Eko nigba naa da obirin naa lola repete.
ABEO: To ba je wipe won ngbiyanju daadaa kilode ti won kofiri ojutu si oro awon alakati kiti boko aram boti leje wipe ojuse awon soja lopoju ninu re.sugbon iru oro to bati ni apakan owo oselu ninu apakan owo oro esin ninu maa n le lopolopo lati yanju.                                                                                                                                                                          
ABEO: oun kan ti mo mo wipe awon olopaa maan sedaradara ni wi pe won mo oko moto dari ti sun kere fa kere bawa. Sugbon ti ara ilu ba pe won wi pe awon adigunjale wa ni ibi kan won a so wipe ko si epo ninu oko awon.
AKANNI: - oga olopa to wa lori aleefa nisinyi nse takuntakun pupo lati ri wipe, olopaa kun oju osuwon lati ripe won ri se ise won gege bi ise. Tori re ni numba awon logaloga se wa kaakiri fun awon eniyan lati pe, lati fejo sun tabi bere fun iranlowo nigba ewu.
ABEO: - se awon olopaa ti ko ni ibon gidi lowo lefe fi koju ole?
AKANNI: - ijoba ngbiyanju lati ra awon ibon igba lode lati fi mu ki ise awon olopaa munadoko, nitori wipe bi oko ti agbe ba mu lo soko ko ba dara, ise re ko ni ya. Eleyii lo fa to fi je wipe awon olopaa wa maa n se daradara  ti won ba lo fun ise mimu alaafia wolu ti awon ajo yueni ba lowon, tori wipe irinse gidi naa nfun won lati lo.
ABEO: - Abala kan tie mi funra mi gbe kansara si awon olopaa fun ni wipe mo wo ye wipe oro andigun jale kopo mo niluwa bii ta ti jomo. Nigbakanri inufuu, edo fuu lawon eniyan maa nwa, sugbon  oni,o kan ti nbale  .Mogba wipe ojuse awon eniyan ki igbe owo to po mo pamo sinu ile bi ta ti jo.
AKANNI: - Ibi kan ti won gbodo gbiyanju si ni oro fifi iya je  awon alaise ti won maa nfi ipa ko. Eto omo niyan ko fa ye gba wipe ki a maa fi iya je afurasi ti adajo ko i ti dajo fun. Opolopo lo maan ku sati mole, ti won kii fi ojubale ejo. Opolopo awon alaise ti won ko mo wo ti won ko mo ese ni won maa n ti mo le. Eleyi ko dara to.
ABEO: - Ofin so wipe ofe ni beeli sugbon iyen ki ise ti awon olopaa o. to ba ti wole lofe, oo ni jade laisan wo.
AKANNI: - Anilo awon olooto ati olufokansin lati darapo mo ise olopaa.

No comments:

Post a Comment