ISE
OSU DARA JU ISE ADANI LO
Ise osu je ise ti o je wi pe
an gbani lati se, eleyii ti adehun yoo wa laarin agbani sise ati eni ti agba
sise lori ise ti an reti re lati se ati iye ti yoo maa gba losoosu. Ise adani
je ise to je wi pe oluwa re lo daa sile oun ni oga ara re, oun loo n pase fun
ara re. Oun lon da gbamoran fun ra re. Bo ti le je wi pe onikaluku okookan awon ise
naa ni won ni
anfaani ati aleebu ti won lara sugbon mo faramo ise adani ni
gbogbo ona ju ise osu lo. Oun akoko ti o maa nba opo eniyan leru ni
wipe ise adani lewu lopo nitori adagbe, adafa. Kini anfani eda laye ti o ba nwa
ibi irorun, ti ko le bo sinu agbami ewu?
Ile aye ti a wa gan ewu ni funrare, a
nsun anji ewu ni funrare, an jade an wole naa ewu ni. Oun kan to maa nko mi
lomi nu lori ise osu ni wipe koka kolaa naa ni o maa njasi ni opolopo igba.
Ogoro awon eyi to poju ninu ise osu lo je wi pe iwonba bukata atije, atimu
nikan ni o gbo, kii saba je ki enyan se bo se wu. Odinwon ti wa lori nkan
teniyan le mu wole. Lakoko, oni se adani kii feyinti, akii jawe
gbele e fun, kii se wi pe nigbati o ba ti fi gbogbo ile aye re sin enikan tan
to wa ndagba ni won awa so fun pe o ti dagba ko maa lo le biti onise osu. Oun
loni ise ati ere re titi laye. Bi koni agbara moo, a file omo lowo, tabi ko gba
awon eniyan si be ko maa fun won lowo osu. Ekeji aladani ni oni gbogbo ere to
ba ri lori owo tabi ise to se. Kii se eyi to je wi pe won maa pin senji die
fun, fun ise tabua to se. Ninu ise osu adehun ladehun nje o. Bi enito ni ile
ise fi osu kan pa ilopo lanaa ogorun iye ti won tii npa tele, iyen ko so wipe o
ni se osu yoo fun un ni idakan ninu ogorun nibe, nitori gege bi adehun, oun
loni gbogbo owo re. Eleeketa, aladani kii jabo fenikeni, oun
loni akoko re bo wuun o ledi oru nibi sere, bo wuu o leti le sere pa ko ma wa
fun ose mefa bo ba ti pa iye owo to fojusun. Ole lo fun isinmi di ye igba to
wuu ni. To ba wuu o le sai ma ya ibi se fun osu meta kii o si maa gba owo re. Ko si orile ede kookan to nmoke lori wi pe
awon onise osu re poju awon ti won ni onise adani pupo tiwon ju onise osu lo.
Eleyii aa mu ki ise wa fun awon eniyan lati se ni ilu. Ole ati ole aadinku ni
awujo. Iran awon onise osu kan kii di oloro ati
borokini. Oni se adani nii di oloro yaa
nturu. Onise osu melo lo je bilionia lagbaye? Bawo ni ba ti ri to baje wi pe
Dangote ngbowo osu ni? Ni bo ni oke aimoye awon ti o gba sise lo ni yoo ti ri
se se? Ema simi gbo o, o ni se osu ledi olowo sugbon akii fise oni se loro
laye, ise ori da ni nise asela. Bi apeere, Orile ede Saina moke lawujo orile
ede agbaye nipa ise adani sise. Bakannaa ni orile ede Indonisia.Bo ti le je wipe ise osu mu ifokanbale ofege
dani ise adani ni baba. Nitori wipe aabo to peye wa fun oko oju omi ni ebute,
sugbon oko oju omi ko wulo ayafi to ba bo sinu agbami omi nla nibiti ewu wa.
Itumo re ni wi pe, nitori lila ewu koja ati bibori ewo ni eleda wa seda wa,
awon ewu kan wa ti akogbodo sa fun ta ba fe moke layee, oun ni se adani, bo ti
le wu to, naa lere ori re po to
No comments:
Post a Comment