Monday, 27 June 2016

IJA IGBORO KAN TI O SELE LAGBEGBE MI



Ija igboro ti o sele ni oju mi, ni agbegbe mi waye ni ojo eti, ojo kejoo osu kini odun ti a wa yi. O waye ni randabaotu Iyana ipaja ni deedee agogo meji osan. Ojo buruku esu gbomimu ni ojo naa je fun enikeni ti oro naa soju re.
Ija yi bere laarin awon awako oko ayokele meji. Ni ojo yiii sunkere -fa -kere oko wa ni oju ona. Ni kete ti eso oju popo sewo si awon oko to n bo lati ori biriji wi pe ki won maa bo ni katakata taa nwi yi sele. Nse ni awako moto Toyota yii fe sare wo aye ti awako Masida kan ye ko sun si, eleyii mu ki awako Masida yi kolu egbe okoToyota yii nibi ti won ti ndu ona mo ra won.

 Ase okan ninu awon oga awon onimoto nasona ni awako Masida, ti Awako Toyota si je omo onile lati Abule Egba. Fara ni awako Toyota boole ti o si lo ba awako Masida nibi tii iyen di elo ituko re mu si, o si tu gbogbo omi ti o wa ninu roba to wa lowo re le awako Masida lori tii se oga awon onimoto, lai mo iru eni to je. Eleyii mu ki gbogbo aso funfun ti Kamoru oga awon onimoto wa di tutu.
Loju ese ni Kamoru ti boole tii Egunleti to je omo onile, lai soro rara Kamoru koko wa awon binuku ekese marun fun oju, imu,ori,eti ati enu Egunleti, laarin iseju aaya oju ati ori Egunleti ti ga gogoro bi eni to soogun iya. Ka to seju pe awon omo Nasona tiri oga won nibi tii o ti nlu Egunleti, won sare si oga won. Gbogbo won ka wo soke po, won si ja ese won  mole leekan naa bi ologun. Nse niwon wa bere si ni lu Egunleti bi kokukoku.
Oun to ya mi lenu ni wi pe ko to iseju marun ti hohuhohu yii sele ni oko Danfo meji yo lookan ti awon ti o wa ninu re sibe sile pelu orisirisi oun ija, awon wonyii ni awon omo onile ti won je eeyan Egunleti, won sare si oju ija won si yin Kamoru, oga awon onimoto nibon leemeji. Awon ota ibon wonyii ko ran an, bee ko si mu oun ija kookan dani sugbon enikeni ti o ba duro gba ese eyo kan pere lowo Kamoru, won n subu lule ni.
 Loju ese naa ni awon omo onimoto naa ti ko oko Danfo marun-un de ti okun fun awon eruuku ati orisiriisi oun ija oloro. Ninu gbogbo eyi ta nso yi ojutiti ti da ko si awon eeyan ninu oko won mo, lo wa di boo lo o yaa mi, igbe aafe we, onikaluku juba ehooro. Awon agbofinro ti won n tuko ona ti poora. Awon to laya akeboje nikan loku nita.
Eje ti bere si ni san, oku ti ndi mewaa, meedogun nile. Awon omo onile ti so ina si opolopo danfo awon onimoto ati awon ayokele gbogbo. Bee ni awon omota nja apamowo,  fonu ati owo awon eniyan gba. Opolopo awon olomoge ati adelebo to ra rin fese si ni won ba sun.
Opelope awon mopoolu kogberegbe ti awon alase ran wa si ibi rogbodiyan naa ni oda wo aawo naa duro. O na awon olopaa yi to wakati kan kii won to ka pa awon egbe mejeeji to n ja,  nitori awon oun ija oloro ti won nlo, ija naa si le gan. O le ni moto ogorun ti won dana sun. Awon olopaa ko gbogbo awon ti won ri sa lo si ago won. Oun to je kayeefi fun mi ni wi pe, ni bo ni awon omo ita ti nri orisiriisi awon oun ija oloro bi ibon atamatase ti won lo ni ojo naa.

Alaroko: Opeifa Gabriel

3 comments: