Abeokuta ni ilu ti o tobi julo
ni ipinle Ogun. Ilu yi fidikale si apa ila oorun odo Ogun. Lara awon oun ti a
le ri ra loja won ni epo pupa, igi gedu, roba, isu, iresi, agbado, owu, ori ati
bee be lo. Idi ti won fi n pe e ni Abeokuta ni wi pe abe ori oke Olumo ni ilu
naa wa.
Oju ona reluwe wa, ti o lo lati
Eko si Abeokuta, o si je kilomita merindinlogorin(77). Won se oju ona reluwe yi
ni 1899. Awon ona miiran ti o tun wo Abeokuta ni Ibadan, Ilaro, Sagamu, Iseyin
ati Ketou.
Sodeke ni o te ilu Abeokuta do ni 1825. Gege bi ibi aabo lowo awon olowo
eru lati Dahomey ati Ibadan. Awon ara Egba ni won koko tedo si Abeokuta.